Num 30:1-2

Num 30:1-2 YBCV

MOSE si sọ fun awọn olori awọn ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ. Bi ọkunrin kan ba jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, tabi ti o ba bura lati fi dè ara rẹ̀ ni ìde, ki on ki o máṣe bà ọ̀rọ rẹ̀ jẹ; ki on ki o ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ẹnu rẹ̀ jade.