Ati li ọjọ́ kẹrinla oṣù kini, ni irekọja OLUWA.
Ati li ọjọ́ kẹdogun oṣù na yi li ajọ: ni ijọ́ meje ni ki a fi jẹ àkara alaiwu.
Li ọjọ́ kini ki apejọ mimọ́ ki o wà; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan:
Ṣugbọn ki ẹnyin ki o ru ẹbọ kan ti a fi iná ṣe, ẹbọ sisun si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu meji, ati àgbo kan, ati akọ ọdọ-agutan meje ọlọdun kan: ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku fun nyin.
Ẹbọ ohunjijẹ wọn iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn ni ki ẹnyin ki o múwa fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo na.
Ati idamẹwa òṣuwọn ni ki iwọ ki o múwa fun ọdọ-agutan kan, fun gbogbo ọdọ-agutan mejeje;
Ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, lati ṣètutu fun nyin.
Ki ẹnyin ki o mú wọnyi wá pẹlu ẹbọ sisun owurọ̀, ti iṣe ti ẹbọ sisun igbagbogbo.
Bayi ni ki ẹnyin rubọ li ọjọjọ́, jalẹ ni ijọ́ mejeje, onjẹ ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA: ki a ru u pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
Ati ni ijọ́ keje ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan.
Li ọjọ́ akọ́so pẹlu, nigbati ẹnyin ba mú ẹbọ ohunjijẹ titun wá fun OLUWA, lẹhin ọsẹ̀ nyin wọnni, ki ẹnyin ki o ní apejọ mimọ́; ẹnyin kò gbọdọ ṣe iṣẹ agbara kan:
Ṣugbọn ki ẹnyin ki o fi ẹgbọrọ akọmalu meji, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan, ru ẹbọ sisun fun õrùn didùn si OLUWA;
Ati ẹbọ ohunjijẹ wọn, iyẹfun ti a fi oróro pò, idamẹwa mẹta òṣuwọn fun akọmalu kan, ati idamẹwa meji òṣuwọn fun àgbo kan,
Ati idamẹwa òṣuwọn fun ọdọ-agutan kan, bẹ̃ni fun ọdọ-agutan mejeje;
Ati obukọ kan, lati ṣètutu fun nyin.
Ki ẹnyin ki o ru wọn pẹlu ẹbọ sisun igba-gbogbo, ati ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀ (ki nwọn ki o jẹ́ alailabùku fun nyin), ati ẹbọ ohunmimu wọn.