OLUWA si sọ fun Mose pe,
Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Ọrẹ-ẹbọ mi, ati àkara mi fun ẹbọ mi ti a fi iná ṣe, fun õrùn didùn si mi, ni ki ẹnyin ma kiyesi lati mú fun mi wá li akokò wọn.
Ki iwọ ki o si wi fun wọn pe, Eyi li ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti ẹnyin o ma múwa fun OLUWA, akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan alailabùku li ojojumọ́, fun ẹbọ sisun igbagbogbo.
Ọdọ-agutan kan ni ki iwọ ki o fi rubọ li owurọ̀, ati ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ;
Ati idamẹwa òṣuwọn efa iyẹfun fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro gigún pò.
Ẹbọ sisun igbagbogbo ni, ti a ti lanasilẹ li òke Sinai fun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
Ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀ ki o jẹ́ idamẹrin òṣuwọn hini fun ọdọ-agutan kan: ni ibi-mimọ ni ki iwọ da ọti lile nì silẹ fun OLUWA fun ẹbọ ohunmimu.
Ọdọ-agutan keji ni ki iwọ ki o fi rubọ li aṣalẹ: bi ẹbọ ohunjijẹ ti owurọ̀, ati bi ẹbọ ohunmimu rẹ̀ ni ki iwọ ki o ṣe, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.
Ati li ọjọ́-isimi akọ ọdọ-agutan meji ọlọdún kan alailabùku, ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun fun ẹbọ ohunjijẹ, ti a fi oróro pò, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀:
Eyi li ẹbọ sisun ọjọjọ́ isimi, pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.
Ati ni ìbẹrẹ òṣu nyin ki ẹnyin ki o ru ẹbọ sisun kan si OLUWA; ẹgbọrọ akọmalu meji, ati àgbo kan, akọ ọdọ-agutan meje ọlọdún kan alailabùku;
Ati idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun akọmalu kan, fun ẹbọ ohunjijẹ; ati idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun àgbo kan, fun ẹbọ ohunjijẹ:
Ati idamẹwa òṣuwọn iyẹfun, ti a fi oróro pò, fun ọdọ-agutan kan fun ẹbọ ohunjijẹ; fun ẹbọ sisun õrùn didùn, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.
Ki ẹbọ ohunmimu wọn ki o jẹ́ àbọ òṣuwọn hini ti ọti-waini fun akọmalu kan, ati idamẹta òṣuwọn hini fun àgbo kan, ati idamẹrin òṣuwọn hini fun ọdọ-agutan kan: eyi li ẹbọ sisun oṣuṣù ni gbogbo oṣù ọdún.
A o si fi obukọ kan ru ẹbọ ẹ̀ṣẹ si OLUWA; pẹlu ẹbọ sisun igbagbogbo, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀.