Balaamu si dide li owurọ̀, o si dì kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ ni gãri, o si bá awọn ijoye Moabu lọ.
Ibinu Ọlọrun si rú nitoriti o lọ: angeli OLUWA si duro loju ọ̀na lati di i lọ̀na. Njẹ on gùn kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, awọn iranṣẹ rẹ̀ mejeji si wà pẹlu rẹ̀.
Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: kẹtẹkẹtẹ na si yà kuro loju ọ̀na, o si wọ̀ inu igbẹ́: Balaamu si lù kẹtẹkẹtẹ na, lati darí rẹ̀ soju ọ̀na.
Nigbana ni angeli OLUWA duro li ọna toro ọgbà-àjara meji, ogiri mbẹ ni ìha ihin, ati ogiri ni ìha ọhún.
Kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o fún ara rẹ̀ mọ́ ogiri, o si fún ẹsẹ̀ Balaamu mọ́ ogiri: on si tun lù u.
Angeli OLUWA si tun sun siwaju, o si tun duro ni ibi tõro kan, nibiti àye kò sí lati yà si ọwọ́ ọtún tabi si òsi.
Nigbati kẹtẹkẹtẹ na si ri angeli OLUWA, o wólẹ̀ labẹ Balaamu: ibinu Balaamu si rú pupọ̀, o si fi ọpá lu kẹtẹkẹtẹ na.
OLUWA si là kẹtẹkẹtẹ na li ohùn, o si wi fun Balaamu pe, Kini mo fi ṣe ọ, ti iwọ fi lù mi ni ìgba mẹta yi?
Balaamu si wi fun kẹtẹkẹtẹ na pe, Nitoriti iwọ fi mi ṣẹsin: idà iba wà li ọwọ́ mi, nisisiyi li emi iba pa ọ.
Kẹtẹkẹtẹ na si wi fun Balaamu pe, Kẹtẹkẹtẹ rẹ ki emi ṣe, ti iwọ ti ngùn lati ìgba ti emi ti ṣe tirẹ titi di oni? emi a ha ma ṣe si ọ bẹ̃ rí? On si dahùn wipe, Ndao.
Nigbana ni OLUWA là Balaamu li oju, o si ri angeli OLUWA duro loju ọ̀na, idà rẹ̀ fifàyọ si wà li ọwọ́ rẹ̀: o si tẹ̀ ori ba, o si doju rẹ̀ bolẹ.
Angeli OLUWA si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi lù kẹtẹkẹtẹ rẹ ni ìgba mẹta yi? Kiyesi i, emi jade wá lati di ọ lọ̀na, nitori ọ̀na rẹ lòdi niwaju mi.
Kẹtẹkẹtẹ na si ri mi, o si yà fun mi ni ìgba mẹta yi: bikoṣe bi o ti yà fun mi, pipa ni emi iba pa ọ, emi a si dá on si.
Balaamu si wi fun angeli OLUWA pe, Emi ti ṣẹ̀; nitori emi kò mọ̀ pe iwọ duro dè mi li ọ̀na; njẹ bi kò ba ṣe didùn inu rẹ, emi o pada.
Angeli OLUWA si wi fun Balaamu pe, Ma bá awọn ọkunrin na lọ: ṣugbọn kìki ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ, eyinì ni ki iwọ ki o sọ. Bẹ̃ni Balaamu bá awọn ijoye Balaki lọ.
Nigbati Balaki gbọ́ pe Balaamu dé, o jade lọ ipade rẹ̀ si Ilu Moabu, ti mbẹ ni àgbegbe Arnoni, ti iṣe ipẹkun ipinlẹ na.
Balaki si wi fun Balaamu pe, Emi kò ha ranṣẹ kanjukanju si ọ lati pè ọ? ẽṣe ti iwọ kò fi tọ̀ mi wá? emi kò ha to lati sọ ọ di ẹni nla?
Balaamu si wi fun Balaki pe, Kiyesi i, emi tọ̀ ọ wá: emi ha lí agbara kan nisisiyi rára lati wi ohun kan? ọ̀rọ ti OLUWA fi si mi li ẹnu, on li emi o sọ.
Balaamu si bá Balaki lọ, nwọn si wá si Kiriati-husotu.
Balaki si rubọ akọmalu ati agutan, o si ranṣẹ si Balaamu, ati si awọn ijoye ti mbẹ pẹlu rẹ̀.
O si ṣe ni ijọ́ keji, ni Balaki mú Balaamu, o si mú u wá si ibi giga Baali, ki o ba le ri apakan awọn enia na lati ibẹ̀ lọ.