Num 2
2
Ètò Pípa Àgọ́ Ní Ẹlẹ́yà-mẹ̀yà
1OLUWA si sọ fun Mose ati fun Aaroni pe,
2Ki olukuluku awọn ọmọ Israeli ki o pa agọ́ rẹ̀ lẹba ọpagun rẹ̀, pẹlu asia ile baba wọn: ki nwọn ki o pagọ́ kọjusi agọ́ ajọ yiká.
3Ki awọn ti iṣe ti ọpagun ibudó Juda ki o dó ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn, gẹgẹ bi ogun wọn: Naṣoni ọmọ Amminadabu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Juda.
4Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilogoji o le ẹgbẹta.
5Ati awọn ti o pagọ́ gbè e ki o jẹ́ ẹ̀ya Issakari: Netaneli ọmọ Suari yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Issakari:
6Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilọgbọ̀n o le irinwo.
7Ati ẹ̀ya Sebuluni: Eliabu ọmọ Heloni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Sebuluni:
8Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mejidilọgbọ̀n o le egbeje.
9Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Juda jẹ́ ẹgba mẹtalelãdọrun o le irinwo, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn yi ni yio kọ́ ṣí.
10Ni ìha gusù ni ki ọpagun ibudó Reubeni ki o wà, gẹgẹ bi ogun wọn: Elisuru ọmọ Ṣedeuru yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Reubeni:
11Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtalelogun o le ẹdẹgbẹta.
12Ati awọn ti o pagọ́ tì i ki o jẹ́ ẹ̀ya Simeoni: Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai ni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Simeoni:
13Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkandilọgbòn o le ẹdegbeje.
14Ati ẹ̀ya Gadi: Eliasafu ọmọ Deueli ni yio si jẹ́ olori ogun ti awọn ọmọ Gadi:
15Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mejilelogun o le ãdọtalelẹgbẹjọ.
16Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Reubeni jẹ́ ẹgba marundilọgọrin o le ãdọtalelegbeje, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikeji.
17Nigbana ni agọ́ ajọ yio si ṣí, pẹlu ibudó, awọn ọmọ Lefi lãrin ibudó: bi nwọn ti dó bẹ̃ni nwọn o ṣí, olukuluku ni ipò rẹ̀, pẹlu ọpagun wọn.
18Ni ìha ìwọ-õrùn ni ki ọpagun ibudó Efraimu ki o wà gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Efraimu:
19Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹta.
20Ati lẹba rẹ̀ ni ki ẹ̀ya Manasse ki o wà: Gamalieli ọmọ Pedahsuru yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Manasse:
21Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹrindilogun o le igba.
22Ati ẹ̀ya Benjamini: Abidani ọmọ Gideoni yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Benjamini:
23Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹtadilogun o le egbeje.
24Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Efraimu, jẹ́ ẹgba mẹrinlelãdọta o le ọgọrun, gẹgẹ bi ogun wọn. Awọn ni yio si ṣí ṣikẹta.
25Ọpagun ibudó Dani ni ki o wà ni ìha ariwa gẹgẹ bi ogun wọn: Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Dani.
26Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mọkanlelọgbọ̀n o le ẹdẹgbẹrin.
27Ati awọn ti o dó tì i ni ki o jẹ́ ẹ̀ya Aṣeri: Pagieli ọmọ Okrani yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Aṣeri:
28Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ọkẹ meji o le ẹdẹgbẹjọ.
29Ati ẹ̀ya Naftali: Ahira ọmọ Enani yio si jẹ́ olori awọn ọmọ Naftali:
30Ati ogun rẹ̀, ati awọn ti a kà ninu wọn, jẹ́ ẹgba mẹrindilọgbọ̀n o le egbeje.
31Gbogbo awọn ti a kà ni ibudó Dani, jẹ́ ẹgba mejidilọgọrin o le ẹgbẹjọ. Awọn ni yio ṣí kẹhin pẹlu ọpagun wọn.
32Eyi li awọn ti a kà ninu awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ile baba wọn: gbogbo awọn ti a kà ni ibudó gẹgẹ bi ogun wọn, jẹ́ ọgbọ̀n ọkẹ o le egbejidilogun din ãdọta.
33Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi li a kò kà mọ́ awọn ọmọ Israeli; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.
34Awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA paṣẹ fun Mose: bẹ̃ni nwọn si dó pẹlu ọpagun wọn, bẹ̃ni nwọn si nṣí, olukuluku nipa idile wọn, gẹgẹ bi ile baba wọn.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Num 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.