Num 15
15
Àwọn Òfin nípa Ìrúbọ
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ ibujoko nyin, ti mo fi fun nyin,
3Ti ẹnyin o ba si ṣe ẹbọ iná si OLUWA, ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ ifẹ́-atinuwá, tabi ninu ajọ nyin lati ṣe õrùn didùn si OLUWA ninu agbo-ẹran, tabi ọwọ́-ẹran:
4Nigbana ni ki ẹniti nru ọrẹ-ẹbọ rẹ̀ na si OLUWA ki o mú ẹbọ ohunjijẹ wá, idamẹwa òṣuwọn iyẹfun ti a fi idamẹrin òṣuwọn hini oróro pò:
5Ati idamẹrin òṣuwọn hini ọti-waini fun ẹbọ ohunmimu ni ki iwọ ki o pèse pẹlu ẹbọ sisun, tabi ẹbọ, fun ọdọ-agutan kan.
6Tabi fun àgbo kan, ki iwọ ki o pèse ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa meji òṣuwọn iyẹfun pẹlu idamẹta òṣuwọn hini oróro:
7Ati fun ẹbọ ohunmimu, ki iwọ ki o mú idamẹta òṣuwọn hini ọti-waini wá, fun õrùn didùn si OLUWA.
8Bi iwọ ba si pèse ẹgbọrọ akọmalu kan fun ẹbọ sisun, tabi fun ẹbọ kan, lati san ẹjẹ́, tabi ẹbọ alafia si OLUWA:
9Nigbana ni ki o mu wá pẹlu ẹgbọrọ akọmalu na, ẹbọ ohunjijẹ idamẹwa mẹta òṣuwọn iyẹfun ti a fi àbọ òsuwọn hini oróro pò.
10Ki iwọ ki o si múwa fun ẹbọ ohunmimu àbọ òṣuwọn hini ọti-waini, ẹbọ ti a fi iná ṣe, õrùn didùn si OLUWA.
11Bayi ni ki a ṣe niti akọmalu kan, tabi niti àgbo kan, tabi niti akọ ọdọ-agutan kan, tabi niti ọmọ-ewurẹ kan.
12Gẹgẹ bi iye ti ẹnyin o pèse, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ṣe si olukuluku gẹgẹ bi iye wọn.
13Gbogbo ibilẹ ni ki o ma ṣe nkan wọnyi bayi, nigbati nwọn ba nru ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA.
14Ati bi alejò kan ba nṣe atipo lọdọ nyin, tabi ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ninu nyin ni iran nyin, ti o si nfẹ́ ru ẹbọ ti a fi iná ṣe, ti õrùn didùn si OLUWA; bi ẹnyin ti ṣe, bẹ̃ni ki on ki o ṣe.
15Ìlana kan ni ki o wà fun ẹnyin ijọ enia, ati fun alejò ti nṣe atipo lọdọ nyin, ìlana titilai, ni iran-iran nyin: bi ẹnyin ti ri, bẹ̃ni ki alejò ki o si ri niwaju OLUWA.
16Ofin kan ati ìlana kan ni ki o wà fun nyin, ati fun alejò ti nṣe atipo lọdọ nyin.
17OLUWA si sọ fun Mose pe,
18Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ na nibiti emi nmú nyin lọ,
19Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba njẹ ninu onjẹ ilẹ na, ki ẹnyin ki o mú ẹbọ igbesọsoke wá fun OLUWA.
20Ki ẹnyin ki o mú àkara atetekọṣu iyẹfun nyin wá fun ẹbọ igbesọsoke: bi ẹnyin ti ṣe ti ẹbọ igbesọsoke ilẹ ipakà, bẹ̃ni ki ẹnyin gbé e sọ.
21Ninu atetekọ́ṣu iyẹfun nyin ni ki ẹnyin ki o fi fun OLUWA li ẹbọ igbesọsoke, ni iran-iran nyin.
22Bi ẹnyin ba si ṣìṣe, ti ẹnyin kò si kiyesi gbogbo ofin wọnyi ti OLUWA ti sọ fun Mose,
23Ani gbogbo eyiti OLUWA ti paṣẹ fun nyin lati ọwọ́ Mose wá, lati ọjọ́ na ti OLUWA ti paṣẹ fun Mose, ati lati isisiyi lọ, ni iran-iran nyin;
24Yio si ṣe, bi a ba fi aimọ̀ ṣe ohun kan ti ijọ kò mọ̀, ki gbogbo ijọ ki o mú ẹgbọrọ akọmalu kan wá fun ẹbọ sisun, fun õrùn didùn si OLUWA, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ rẹ̀, ati ẹbọ ohunmimu rẹ̀, gẹgẹ bi ìlana na, ati obukọ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.
25Ki alufa ki o si ṣètutu fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, a o si darijì wọn; nitoripe aimọ̀ ni, nwọn si ti mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA, ati ẹbọ ẹ̀ṣẹ wọn niwaju OLUWA, nitori aimọ̀ wọn:
26A o si darijì gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, ati alejò ti iṣe atipo lọdọ wọn; nitoripe gbogbo enia wà li aimọ̀.
27Bi ọkàn kan ba si fi aimọ̀ ṣẹ̀, nigbana ni ki o mú abo-ewurẹ ọlọdún kan wá, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ.
28Ki alufa ki o ṣètutu fun ọkàn na ti o ṣẹ̀, nigbati o ba ṣẹ̀ li aimọ̀ niwaju OLUWA, lati ṣètutu fun u; a o si darijì i.
29Ofin kan ni ki ẹnyin ki o ní fun ẹniti o ṣẹ̀ ni aimọ̀, ati fun ẹniti a bi ninu awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo ninu wọn.
30Ṣugbọn ọkàn na ti o ba fi ikugbu ṣe ohun kan, iba ṣe ibilẹ tabi alejò, o sọ̀rọbuburu si OLUWA; ọkàn na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.
31Nitoriti o gàn ọ̀rọ OLUWA, o si ru ofin rẹ̀; ọkàn na li a o ke kuro patapata, ẹ̀ṣẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀.
32Nigbati awọn ọmọ Israeli wà li aginjù, nwọn ri ọkunrin kan ti nṣẹ́ igi li ọjọ́-isimi.
33Awọn ti o ri i ti nṣẹ́ igi mú u tọ̀ Mose ati Aaroni wá, ati gbogbo ijọ.
34Nwọn si há a mọ́ ile-ìde, nitoriti a kò ti isọ bi a o ti ṣe e.
35OLUWA si sọ fun Mose pe, Pipa li a o pa ọkunrin na: gbogbo ijọ ni yio sọ ọ li okuta pa lẹhin ibudó.
36Gbogbo ijọ si mú u wá sẹhin ibudó, nwọn si sọ ọ li okuta, on si kú; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.
Òfin nípa Kókó Etí Aṣọ
37OLUWA si sọ fun Mose pe,
38Sọ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si fi aṣẹ fun wọn ki nwọn ki o ṣe wajawaja si eti aṣọ wọn ni iran-iran wọn, ati ki nwọn ki o si fi ọjábulẹ alaró si wajawaja eti aṣọ na:
39Yio si ma ṣe bi wajawaja fun nyin, ki ẹnyin ki o le ma wò o, ki ẹ si ma ranti gbogbo ofin OLUWA, ki ẹ si ma ṣe wọn: ki ẹnyin ki o má si ṣe tẹle ìro ọkàn nyin ati oju ara nyin, ti ẹnyin ti ima ṣe àgbere tọ̀ lẹhin:
40Ki ẹnyin ki o le ma ranti, ki ẹ si ma ṣe ofin mi gbogbo, ki ẹnyin ki o le jẹ́ mimọ́ si Ọlọrun nyin.
41Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin, ti o mú nyin jade lati ilẹ Egipti wá, lati ma ṣe Ọlọrun nyin: Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Num 15: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.