Num 10

10
Àwọn Fèrè Fadaka
1OLUWA si sọ fun Mose pe,
2Iwọ ṣe ipè fadakà meji; iṣẹ́-ọnà lilù ni ki o ṣe wọn: iwọ o si ma fi wọn pè ajọ, iwọ o si ma fi wọn ṣí ibudó.
3Nigbati nwọn ba fun wọn, ki gbogbo ijọ ki o pé sọdọ rẹ li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.
4Bi o ba ṣepe ipè kan ni nwọn fun, nigbana ni ki awọn ijoye, olori ẹgbẹgbẹrun enia Israeli, ki o pejọ sọdọ rẹ.
5Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha ìla-õrùn ki o ṣí siwaju.
6Nigbati ẹnyin ba si fun ipè idagiri nigba keji, nigbana ni ki awọn ibudó ti o wà ni ìha gusù ki o ṣì siwaju: ki nwọn ki o si fun ipè idagiri ṣíṣi wọn.
7Ṣugbọn nigbati a o ba pè ijọ pọ̀, ki ẹ fun ipè, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ fun ti idagiri.
8Awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, ni ki o si fun ipè na; ki nwọn ki o si ma ṣe ìlana lailai fun nyin ni iran-iran nyin.
9Bi ẹnyin ba si lọ si ogun ni ilẹ nyin lọ ipade awọn ọtá ti nni nyin lara, nigbana ni ki ẹnyin ki o fi ipè fun idagiri; a o si ranti nyin niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, a o si gbà nyin lọwọ awọn ọtá nyin.
10Li ọjọ̀ ayọ̀ nyin pẹlu, ati li ajọ nyin, ati ni ìbẹrẹ oṣù nyin, ni ki ẹnyin ki o fun ipè sori ẹbọ sisun nyin, ati sori ẹbọ ti ẹbọ alafia nyin; ki nwọn ki o le ma ṣe iranti fun nyin niwaju Ọlọrun nyin: Emi ni OLUWA Ọlọrun nyin.
Àwọn Ọmọ Israẹli Ṣí Àgọ́ Wọn
11O si ṣe li ogun ọjọ́ oṣù keji, li ọdún keji, ni awọsanma ká soke kuro lori agọ́ ẹrí.
12Awọn ọmọ Israeli si dide ìrin wọn lati ijù Sinai; awọsanma na si duro ni ijù Parani.
13Nwọn si bẹ̀rẹsi iṣí gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA nipa ọwọ́ Mose.
14Ọpágun ibudó awọn ọmọ Juda si kọ́ ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Naṣoni ọmọ Amminadabu.
15Olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari si ni Netaneli ọmọ Suari.
16Olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Sebuluni ni Eliabu ọmọ Heloni.
17A si tú agọ́ na palẹ; awọn ọmọ Gerṣoni, ati awọn ọmọ Merari ti nrù agọ́ si ṣí.
18Ọpágun ibudó Reubeni si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: Elisuri ọmọ Ṣedeuri si li olori ogun rẹ̀.
19Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni ni Ṣelumieli ọmọ Suriṣaddai.
20Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Gadi ni Eliasafu ọmọ Deueli.
21Awọn ọmọ Kohati ti nrù ohun mimọ́ si ṣí: awọn ti iṣaju a si ma gbé agọ́ ró dè atidé wọn.
22Ọpágun ibudó awọn ọmọ Efraimu si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: Eliṣama ọmọ Ammihudu si li olori ogun rẹ̀.
23Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse ni Gamalieli ọmọ Pedasuri.
24Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini ni Abidani ọmọ Gideoni.
25Ọpágun ibudó awọn ọmọ Dani, ti o kẹhin gbogbo ibudó, si ṣí gẹgẹ bi ogun wọn: olori ogun rẹ̀ si ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.
26Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri ni Pagieli ọmọ Okrani.
27Ati olori ogun ẹ̀ya awọn ọmọ Naftali ni Ahira ọmọ Enani.
28Bayi ni ìrin awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ogun wọn; nwọn si ṣí.
29Mose si wi fun Hobabu, ọmọ Ragueli ara Midiani, ana Mose pe, Awa nṣí lọ si ibi ti OLUWA ti wi pe, Emi o fi i fun nyin: wá ba wa lọ, awa o ṣe ọ li ore: nitoripe OLUWA sọ̀rọ rere nipa Israeli.
30On si wi fun u pe, Emi ki yio lọ; ṣugbọn emi o pada lọ si ilẹ mi, ati sọdọ ará mi.
31O si wipe, Máṣe fi wa silẹ, emi bẹ̀ ọ; iwọ sà mọ̀ pe ni ijù li awa dó si, iwọ o si ma ṣe oju fun wa.
32Yio si ṣe, bi iwọ ba bá wa lọ, yio si ṣe, pe, orekore ti OLUWA ba ṣe fun wa, on na li awa o ṣe fun ọ.
Àwọn Eniyan náà Tẹ̀síwájú
33Nwọn si ṣí kuro ni òke OLUWA ni ìrin ijọ́ mẹta: apoti majẹmu OLUWA si ṣiwaju wọn ni ìrin ijọ́ mẹta, lati wá ibi isimi fun wọn.
34Awọsanma OLUWA mbẹ lori wọn li ọsán, nigbati nwọn ba ṣí kuro ninu ibudó.
35O si ṣe, nigbati apoti ẹrí ba ṣí siwaju, Mose a si wipe, Dide, OLUWA, ki a si tú awọn ọtá rẹ ká; ki awọn ti o korira rẹ ki o si salọ kuro niwaju rẹ.
36Nigbati o ba si simi, on a wipe, Pada, OLUWA, sọdọ ẹgbẹgbarun awọn enia Israeli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Num 10: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀