Awọn ọta wa si wipe, Nwọn kì yio mọ̀, bẹ̃ni nwọn kì yio ri titi awa o fi de ãrin wọn, ti a o fi pa wọn, ti a o si da iṣẹ na duro.
O si ṣe, nigbati awọn ara Juda ti o wà li agbegbe wọn de, nwọn wi fun wa nigba mẹwa pe, Lati ibi gbogbo wá li ẹnyin o pada tọ̀ wa wá.
Nitorina ni mo yàn awọn enia si ibi ti o rẹlẹ lẹhin odi, ati si ibi gbangba, mo tilẹ yàn awọn enia gẹgẹ bi idile wọn, pẹlu idà wọn, ọ̀kọ wọn, ati ọrun wọn.
Mo si wò, mo si dide, mo si wi fun awọn ìjoye, ati fun awọn olori, ati fun awọn enia iyokù pe, Ẹ máṣe jẹ ki ẹ̀ru wọn bà nyin, ẹ ranti Oluwa ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ki ẹ si jà fun awọn arakunrin nyin, awọn ọmọkunrin nyin, ati awọn ọmọbinrin nyin, awọn aya nyin, ati ile nyin.
O si ṣe, nigbati awọn ọta wa gbọ́ pe, o di mimọ̀ fun wa, Ọlọrun ti sọ ìmọ wọn di asan, gbogbo wa si padà si odi na, olukuluku si iṣẹ rẹ̀.
O si ṣe, lati ọjọ na wá, idaji awọn ọmọkunrin mi ṣe iṣẹ na, idaji keji di ọ̀kọ, apata, ati ọrun, ati ihamọra mu; awọn olori si duro lẹhin gbogbo ile Juda.
Awọn ti nmọ odi, ati awọn ti nrù ẹrù ati awọn ti o si ndi ẹrù, olukuluku wọn nfi ọwọ rẹ̀ kan ṣe iṣẹ, nwọn si fi ọwọ keji di ohun ìja mu.
Olukuluku awọn ọmọ kọ́ idà rẹ̀ li ẹgbẹ rẹ̀, bẹni nwọn si mọ odi. Ẹniti nfọn ipè wà li eti ọdọ mi.