Neh 2
2
Nehemiah lọ sí Jerusalẹmu
1O si ṣe li oṣu Nisani, li ogún ọdun Artasasta ọba, ọti-waini wà niwaju rẹ̀: mo si gbe ọti-waini na, mo si fi fun ọba. Emi kò si ti ifajuro niwaju rẹ̀ rí.
2Nitorina ni ọba ṣe wi fun mi pe, ẽṣe ti oju rẹ fi faro? iwọ kò sa ṣaisan? eyi kì iṣe ohun miran bikoṣe ibanujẹ. Ẹ̀ru si ba mi gidigidi.
3Mo si wi fun ọba pe, Ki ọba ki o pẹ: ẽṣe ti oju mi kì yio fi faro, nigbati ilu, ile iboji awọn baba mi dahoro, ti a si fi iná sun ilẹkun rẹ̀?
4Nigbana ni ọba wi fun mi pe, ẹ̀bẹ kini iwọ fẹ bẹ̀? Bẹ̃ni mo gbadura si Ọlọrun ọrun.
5Mo si wi fun ọba pe, Bi o ba wù ọba, ati bi iranṣẹ rẹ ba ri ojurere lọdọ rẹ, ki iwọ le rán mi lọ si Juda, si ilu iboji awọn baba mi, ki emi ki o ba le kọ́ ọ.
6Ọba si wi fun mi pe, (ayaba si joko tì i) ajo rẹ yio ti pẹ to? nigbawo ni iwọ o si pada? Bẹli o wù ọba lati rán mi; mo si dá àkoko kan fun u.
7Pẹlupẹlu mo wi fun ọba pe, bi o ba wù ọba, ki o fun mi ni iwe si awọn bãlẹ li oke odò, ki nwọn le mu mi kọja titi emi o fi de Juda;
8Ati iwe kan fun Asafu, oluṣọ igbo ọba, ki o le fun mi ni igi fun atẹrigba ẹnu-ọ̀na odi lẹba ile Ọlọrun ati fun odi ilu, ati fun ile ti emi o wọ̀. Ọba si fun mi gẹgẹ bi ọwọ rere Ọlọrun mi lara mi.
9Nigbana ni mo de ọdọ awọn bãlẹ li oke odo mo si fi iwe ọba fun wọn: Ọba si ti rán awọn olori-ogun ati ẹlẹṣin pẹlu mi.
10Nigbati Sanballati ara Horoni ati Tobiah iranṣẹ ara Ammoni gbọ́, o bi wọn ni inu gidigidi pe, enia kan wá lati wá ire awọn ọmọ Israeli.
11Bẹni mo de Jerusalemu, mo si wà nibẹ̀ ni ọjọ mẹta.
12Mo si dide li oru, emi ati ọkunrin diẹ pẹlu mi: emi kò si sọ fun enia kan ohun ti Ọlọrun mi fi si mi li ọkàn lati ṣe ni Jerusalemu: bẹni kò si ẹranko kan pẹlu mi, bikoṣe ẹranko ti mo gùn.
13Mo si jade li oru ni ibode afonifoji, ani niwaju kanga Dragoni, ati li ẹnu-ọ̀na ãtàn; mo si wò odi Jerusalemu ti a wó lulẹ̀, ati ẹnu-ọ̀na ti a fi iná sun.
14Nigbana ni mo lọ si ẹnu-ọ̀na orisun, ati si àbata ọba: ṣugbọn kò si àye fun ẹranko ti mo gun lati kọja.
15Nigbana ni mo goke lọ li oru lẹba odò, mo si wò odi na: mo si yipada, mo si tún wọ̀ bode afonifoji, mo si yipada.
16Awọn ijoye kò si mọ̀ ibi ti mo lọ, tabi ohun ti mo ṣe; emi kò ti isọ fun awọn ara Juda tabi fun awọn alufa, tabi fun awọn alagba, tabi fun awọn ijoye; tabi fun awọn iyokù ti o ṣe iṣẹ na.
17Nigbana ni mo wi fun wọn pe, Ẹnyin ri ibanujẹ ti awa wà, bi Jerusalemu ti di ahoro, ẹnu-ọ̀na rẹ̀ li a si fi iná sun: ẹ wá, ẹ jẹ ki a mọ odi Jerusalemu, ki a má ba jẹ ẹni-ẹgàn mọ!
18Nigbana ni mo si sọ fun wọn niti ọwọ Ọlọrun mi, ti o dara li ara mi; ati ọ̀rọ ọba ti o ba mi sọ. Nwọn si wipe, Jẹ ki a dide, ki a si mọ odi! Bẹni nwọn gba ara wọn ni iyanju fun iṣẹ rere yi.
19Ṣugbọn nigbati Sanballati ara Horoni, ati Tobiah iranṣẹ, ara Ammoni, ati Gesẹmu, ara Arabia, gbọ́, nwọn fi wa rẹrin ẹlẹya, nwọn si gàn wa, nwọn si wipe, Kini ẹnyin nṣe yi? ẹnyin o ha ṣọ̀tẹ si ọba bi?
20Nigbana ni mo da wọn li ohùn mo si wi fun wọn pe, Ọlọrun ọrun, On o ṣe rere fun wa; nitorina awa iranṣẹ rẹ̀ yio dide lati mọ odi: ṣugbọn ẹnyin kò ni ipin tabi ipa tabi ohun iranti ni Jerusalemu.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Neh 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.