Neh 12

12
Orúkọ Àwọn Alufaa ati Àwọn Ọmọ Lefi
1WỌNYI si ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi ti o ba Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli goke lọ, ati Jeṣua: Seraiah Jeremiah, Esra,
2Amariah, Malluki, Hattuṣi,
3Ṣekaniah, Rehumu, Meremoti,
4Iddo, Ginneto, Abijah,
5Miamini, Maadiah, Bilga,
6Ṣemaiah, ati Joiaribu, Jodaiah,
7Sallu, Amoku, Hilkiah, Jedaiah. Wọnyi li olori awọn alufa, ati ti awọn arakunrin wọn li ọjọ Jeṣua.
8Ati awọn ọmọ Lefi: Jeṣua, Binnui, Kadmieli, Ṣerebiah, Juda, ati Mattaniah, ti o wà lori orin idupẹ, on ati awọn arakunrin rẹ̀.
9Bakbukiah pẹlu ati Unni, awọn arakunrin wọn, li o kọju si wọn ninu iṣọ.
Àwọn Ìran Jeṣua Olórí Àlùfáà
10Jeṣua si bi Joiakimu, Joiakimu si bi Eliaṣibu, Eliaṣibu si bi Joiada,
11Joiada si bi Jonatani, Jonatani si bi Jaddua.
Àwọn Baálé Baálé ní Ìdílé Àwọn Àlùfáà
12Ninu awọn alufa li ọjọ Joiakimu li awọn olori awọn baba wà: ti Seraiah, Meraiah; ti Jeremiah, Hananiah;
13Ti Esra, Meṣullamu; ti Amariah, Jehohanani;
14Ti Meliku, Jonatani; ti Ṣebaniah, Josefu;
15Ti Harimu, Adna; ti Meraioti, Helkai;
16Ti Iddo, Sekariah; ti Ginnetoni, Meṣullamu;
17Ti Abijah, Sikri; ti Miniamini, ti Moadiah, Piltai:
18Ti Bilga, Sammua; ti Ṣemaiah, Jehonatani;
19Ati ti Joaribu, Mattenai; ti Jedaiah, Ussi;
20Ti Sallai, Killai; ti Amoku, Eberi;
21Ti Hilkiah, Haṣhabiah; ti Jedaiah, Netaneeli;
22Ninu awọn ọmọ Lefi li ọjọ Eliaṣibu, Joiada, ati Johanani, ati Jaddua, awọn olori awọn baba: li a kọ sinu iwe pẹlu awọn alufa, titi di ijọba Dariusi ara Perṣia.
23Awọn ọmọ Lefi, olori awọn baba li a kọ sinu iwe itan titi di ọjọ Johanani ọmọ Eliaṣibu.
Ìlànà Iṣẹ́ inú Tẹmpili
24Awọn olori awọn ọmọ Lefi si ni Haṣabiah, Ṣerebiah, ati Jeṣua ọmọ Kadmieli, pẹlu awọn arakunrin wọn kọju si ara wọn, lati yìn ati lati dupẹ, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi enia Ọlọrun, li ẹgbẹgbẹ ẹṣọ.
25Mattaniah, ati Bakbukiah, Obadiah, Meṣullamu, Talmoni, Akkubu, jẹ adèna lati ma ṣọ ìloro ẹnu-ọ̀na.
26Wọnyi wà li ọjọ Joiakimu, ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, ati li ọjọ Nehemiah bãlẹ, ati Esra alufa, ti iṣe akọwe.
Nehemiah Ṣe Ìyàsímímọ́ Odi Ìlú náà
27Ati nigba yiya odi Jerusalemu si mimọ́, nwọn wá awọn ọmọ Lefi kiri ninu gbogbo ibugbe wọn, lati mu wọn wá si Jerusalemu lati fi ayọ̀ ṣe iyà si mimọ́ na pẹlu idupẹ ati orin, pẹlu simbali, psalteri, ati pẹlu dùru.
28Awọn ọmọ awọn akọrin si ko ara wọn jọ lati pẹ̀tẹlẹ yi Jerusalemu ka, ati lati ileto Netofati wá;
29Lati ile Gilgali wá pẹlu, ati lati inu ilẹ Geba ati Asmafeti, nitori awọn akọrin ti kọ ileto fun ara wọn yi Jerusalemu kakiri.
30Ati awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi wẹ̀ ara wọn mọ́, nwọn si wẹ̀ awọn enia mọ́, ati ẹnu-bode, ati odi.
31Nigbana ni mo mu awọn ijoye Juda wá si ori odi, mo si yàn ẹgbẹ nla meji, ninu awọn ti ndupẹ, ẹgbẹ kan lọ si apa ọtun li ori odi, siha ẹnu-bode àtan.
32Hoṣaiah si lọ tẹle wọn ati idaji awọn ijoye Juda.
33Ati Asariah, Esra, ati Meṣullamu,
34Juda, ati Benjamini, ati Ṣemaiah ati Jeremiah.
35Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa mu fère lọwọ, Sekariah, ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mikaiah, ọmọ Sakkuri, ọmọ Asafu:
36Ati awọn arakunrin rẹ̀, Ṣemaiah, ati Asaraeli, Milalai, Gilalai, Maai, Netaneeli, ati Juda, Hanani, pẹlu ohun èlo orin Dafidi, enia Ọlọrun, ati Esra akọwe niwaju wọn.
37Ati ni ẹnu-bode orisun eyi ni ibi ti o kọju si i, nwọn ba àtẹgun ilu Dafidi goke lọ, ni ibi odi ti o goke lọ, ni ikọja ile Dafidi, titi de ẹnu-bode omi, niha ila õrùn.
38Ati ẹgbẹ keji awọn ti ndupẹ, lọ li odi keji si wọn, ati emi lẹhin wọn, pẹlu idaji awọn enia lori odi, lati ikọja ile iṣọ ileru, titi de odi gbigboro.
39Nwọn si rekọja oke ẹnu-bode Efraimu wá, ati lati oke ẹnu-bode lailai ati li oke ẹnu-bode ẹja, ati ile-iṣọ Hananieli, ati ile-iṣọ Mea, titi de ẹnu-bode agutan, nwọn si duro li ẹnu-bode tubu.
40Bayi ni awọn ẹgbẹ meji ti ndupẹ ninu ile Ọlọrun duro, ati emi ati idaji awọn ijoye pẹlu mi.
41Ati awọn alufa: Eliakimu, Maaseiah, Miniamini Mikaiah, Elioenai, Sekariah, Hananiah mu fère lọwọ;
42Ati Maaseiah, ati Ṣemaiah, ati Eleasari, ati Ussi, ati Jehohanani, ati Malkijah, ati Elamu, ati Eseri, awọn akọrin kọrin soke, pẹlu Jesrahiah alabojuto.
43Li ọjọ na pẹlu nwọn ṣe irubọ nla, nwọn si yọ̀ nitori Ọlọrun ti mu wọn yọ̀ ayọ̀ nla, aya wọn ati awọn ọmọde yọ̀ pẹlu, tobẹ̃ ti a si gbọ́ ayọ̀ Jerusalemu li okere reré.
Pípèsè fún Ìjọ́sìn Ní Tẹmpili
44Li akoko na li a si yàn awọn kan ṣe olori yara iṣura, fun ọrẹ-ẹbọ, fun akọso, ati fun idamẹwa, lati ma ko ipin ti a yàn jọ lati oko ilu wọnni wá, ti ofin fun awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi: nitoriti Juda yọ̀ fun awọn ọmọ Lefi ti o duro.
45Ati awọn akọrin, ati adèna npa ẹṣọ Ọlọrun wọn mọ, ati ẹṣọ iwẹnumọ́, gẹgẹ bi aṣẹ Dafidi; ati ti Solomoni ọmọ rẹ̀.
46Nitori li ọjọ Dafidi ati Asafu nigbani awọn olori awọn akọrin wà, ati orin iyìn, ati ọpẹ fun Ọlọrun.
47Gbogbo Israeli li ọjọ Serubbabeli, ati li ọjọ Nehemiah si fi ipin awọn akọrin, ati ti awọn adèna fun wọn olukuluku ni ipin tirẹ̀ li ojojumọ, nwọn si ya ohun mimọ́ awọn ọmọ Lefi si ọ̀tọ, awọn ọmọ Lefi si yà wọn si ọ̀tọ fun awọn ọmọ Aaroni.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Neh 12: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀