Neh 1
1
1Ọ̀RỌ Nehemiah ọmọ Hakaliah. O si ṣe ninu oṣu Kisleu, ni ogún ọdun, nigba tí mo wà ni Ṣuṣani ãfin.
Ẹ̀dùn Ọkàn Nehemiah fún Jerusalẹmu
2Ni Hanani, ọkan ninu awọn arakunrin mi, on ati awọn ọkunrin kan lati Juda wá sọdọ mi; mo si bi wọn lere niti awọn ara Juda ti o salà, ti o kù ninu awọn igbekùn, ati niti Jerusalemu.
3Nwọn si wi fun mi pe, Awọn iyokù, ti a fi silẹ nibẹ ninu awọn igbekùn ni igberiko, mbẹ ninu wahala nla ati ẹ̀gan; odi Jerusalemu si wó lulẹ̀, a si fi ilẹkùn rẹ̀ joná.
4O si ṣe nigbati mo gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, mo joko, mo si sọkun, mo si ṣọ̀fọ ni iye ọjọ, mo si gbãwẹ, mo si gbàdura niwaju Ọlọrun ọrun.
5Mo si wipe, Emi mbẹ̀bẹ lọdọ rẹ, Oluwa Ọlọrun ọrun, ti o tobi, ti o si li ẹ̀ru, ti npa majẹmu ati ãnu mọ fun awọn ti o fẹ ẹ, ti nwọn si pa ofin rẹ̀ mọ:
6Tẹ́ eti rẹ silẹ̀ nisisiyi, ki o si ṣi oju rẹ, ki iwọ ba le gbọ́ adura iranṣẹ rẹ, ti mo ngbà niwaju rẹ nisisiyi, tọsan toru fun awọn ọmọ Israeli iranṣẹ rẹ, ti mo si jẹwọ ẹ̀ṣẹ awọn ọmọ Israeli ti a ti ṣẹ̀ si ọ: ati emi ati ile baba mi ti ṣẹ̀.
7Awa ti huwa ibàjẹ si ọ, awa kò si pa ofin ati ilana ati idajọ mọ, ti iwọ pa li aṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ.
8Emi bẹ̀ ọ, ranti ọ̀rọ ti iwọ pa laṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ, wipe, Bi ẹnyin ba ṣẹ̀, emi o tú nyin kakiri sãrin awọn orilẹ-ède:
9Ṣugbọn bi ẹnyin ba yipada si mi, ti ẹ si pa ofin mi mọ, ti ẹ si ṣe wọn, bi o tilẹ ṣepe ẹnyin ti a ti tì jade wà ni ipẹkun ọrun, emi o ko wọn jọ lati ibẹ wá, emi o si mu wọn wá si ibi ti mo ti yàn lati fi orukọ mi si.
10Njẹ awọn wọnyi ni awọn iranṣẹ rẹ ati enia rẹ, ti iwọ ti rà pada nipa agbara rẹ nla ati nipa ọwọ agbara rẹ.
11Oluwa, emi bẹ ọ, tẹ́ eti rẹ silẹ si adura iranṣẹ rẹ, ati si adura awọn iranṣẹ rẹ, ti o fẹ lati bẹ̀ru orukọ rẹ: emi bẹ ọ, ki o si ṣe rere si iranṣẹ rẹ loni, ki o si fun u li ãnu li oju ọkunrin yi. Nitori agbe-ago ọba li emi jẹ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Neh 1: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.