Nah 3
3
1EGBE ni fun ilu ẹjẹ̀ nì! gbogbo rẹ̀ kun fun eké, ati olè, ijẹ kò kuro;
2Ariwo pàṣan, ati ariwo kikùn kẹkẹ́, ati ti ijọ awọn ẹṣin, ati ti fifò kẹkẹ́.
3Ẹlẹṣin ti gbe idà rẹ̀ ti nkọ màna, ati ọkọ̀ rẹ̀ ti ndán yànran si oke: ọ̀pọlọpọ si li awọn ẹniti a pa, ati ọ̀pọlọpọ okú; okú kò si ni opin; nwọn nkọsẹ̀ li ara okú wọn wọnni:
4Nitori ọ̀pọlọpọ awọn panṣagà àgbere ti o roju rere gbà, iya ajẹ ti o ntà awọn orilẹ-ède nipasẹ̀ panṣaga rẹ̀, ati idile nipasẹ̀ ajẹ rẹ̀.
5Kiyesi i, emi dojukọ́ ọ, ni Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; emi o si ká aṣọ itẹlẹ̀di rẹ li oju rẹ, emi o si fi ihòho rẹ hàn awọn orilẹ-ède, ati itiju rẹ hàn awọn ilẹ̀ ọba.
6Emi o da ẹgbin ti o ni irira si ọ lara, emi o si sọ ọ di alaimọ́, emi o si gbe ọ kalẹ bi ẹni ifiṣẹlẹyà.
7Yio si ṣe pe, gbogbo awọn ti o wò ọ yio sa fun ọ, nwọn o si wipe, A ti fi Ninefe ṣòfo: tani yio kẹdùn rẹ̀? nibo ni emi o ti wá olutùnu fun ọ?
8Iwọ ha sàn jù No-ammoni, eyiti o wà lãrin odò ti omi yika kiri, ti agbara rẹ̀ jẹ okun, ti odi rẹ̀ si ti inu okun jade wá?
9Etiopia ati Egipti li agbara rẹ̀, kò si li opin; Puti ati Lubimu li awọn olùranlọwọ rẹ.
10Sibẹ̀sibẹ̀ a kó o lọ, o lọ si oko-ẹrú: awọn ọmọ wẹ́wẹ rẹ̀ li a fi ṣánlẹ̀ pẹlu li ori ita gbogbo; nwọn si di ibò nitori awọn ọlọla rẹ̀ ọkunrin, gbogbo awọn ọlọla rẹ̀ li a si fi ẹwọ̀n dì.
11Iwọ pẹlu o si yó ọti; a o si fi ọ pamọ, iwọ pẹlu o si ma ṣe afẹri ãbò nitori ti ọta na.
12Gbogbo ile-iṣọ agbara rẹ yio dabi igi ọpọ̀tọ pẹlu akọpọn ọpọ̀tọ: bi a ba gbọ̀n wọn, nwọn o si bọ si ẹnu ọjẹun.
13Kiye si i, obinrin li awọn enia rẹ lãrin rẹ: oju ibodè ilẹ rẹ li a o ṣi silẹ gbaguda fun awọn ọta rẹ: iná yio jo ikere rẹ.
14Iwọ pọn omi de ihamọ, mu ile iṣọ rẹ le: wọ̀ inu amọ̀, ki o si tẹ̀ erupẹ̀, ki o si ṣe ibiti a nsun okuta-amọ̀ ki o le.
15Nibẹ̀ ni iná yio jo ọ run; idà yio ké ọ kuro, yio si jẹ ọ bi kòkoro: sọ ara rẹ di pupọ̀ bi kòkoro, si sọ ara rẹ di pupọ̀ bi ẽṣu.
16Iwọ ti sọ awọn oniṣòwo rẹ di pupọ̀ jù iràwọ oju ọrun lọ: kokòro nà ara rẹ̀, o si fò lọ.
17Awọn alade rẹ dabi eṣú, awọn ọgagun rẹ si dabi ẹlẹngà nla, eyiti ndó sinu ọgbà la ọjọ otutù, ṣugbọn nigbati õrùn là, nwọn sa lọ, a kò si mọ̀ ibiti wọn gbe wà.
18Awọn olùṣọ agùtan rẹ ntõgbe, Iwọ ọba Assiria: awọn ọlọla rẹ yio ma gbe inu ekuru: awọn enia rẹ si tuka lori oke-nla, ẹnikan kò si kó wọn jọ.
19Kò si ipajumọ fun ifarapa rẹ; ọgbẹ rẹ kún fun irora, gbogbo ẹniti o gbọ́ ihin rẹ yio pàtẹwọ le ọ lori, nitori li ori tani ìwa-buburu rẹ kò ti kọja nigbagbogbo?
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Nah 3: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.