Nigbati nwọn si de ọdọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn ri ijọ enia pipọ lọdọ wọn, awọn akọwe si mbi wọn lẽre ọ̀ran.
Lọgan nigbati gbogbo enia si ri i, ẹnu si yà wọn gidigidi, nwọn si sare tọ ọ nwọn nki i.
O si bi awọn akọwe, wipe, Kili ẹnyin mbère lọwọ wọn?
Ọkan ninu ijọ enia na si dahùn, wipe, Olukọni, mo mu ọmọ mi ti o ni odi, ẹmi tọ̀ ọ wá;
Nibikibi ti o ba gbé si mu u, a si ma nà a tantan: on a si ma yọ ifofó li ẹnu, a si ma pahin keke, a si ma daku; mo si sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ, ki nwọn lé e jade; nwọn ko si le ṣe e.
O si da wọn lohùn, o si wipe, Iran alaigbagbọ́ yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? ẹ mu u wá sọdọ mi.
Nwọn si mu u wá sọdọ rẹ̀: nigbati o si ri i, lojukanna ẹmi nã nà a tantan; o si ṣubu lulẹ o si nfi ara yilẹ o si nyọ ifofó li ẹnu.
O si bi baba rẹ̀ lẽre, wipe, O ti pẹ to ti eyi ti de si i? O si wipe, Lati kekere ni.
Nigbakugba ni si ima gbé e sọ sinu iná, ati sinu omi, lati pa a run: ṣugbọn bi iwọ ba le ṣe ohunkohun, ṣãnu fun wa, ki o si ràn wa lọwọ.
Jesu si wi fun u pe, Bi iwọ ba le gbagbọ́, ohun gbogbo ni ṣiṣe fun ẹniti o ba gbagbọ́.
Lojukanna baba ọmọ na kigbe li ohùn rara, o si fi omije wipe, Oluwa, mo gbagbọ́; ràn aigbagbọ́ mi lọwọ.
Nigbati Jesu si ri pe ijọ enia nsare wọjọ pọ̀, o ba ẹmi aimọ́ na wi, o wi fun u pe, Iwọ odi ati aditi ẹmi, mo paṣẹ fun ọ, jade lara rẹ̀, ki iwọ má ṣe wọ̀ inu rẹ̀ mọ́.
On si kigbe soke, o si nà a tàntàn, o si jade lara rẹ̀: ọmọ na si dabi ẹniti o kú; tobẹ ti ọpọlọpọ fi wipe, O kú.
Ṣugbọn Jesu mu u li ọwọ́, o si fà a soke; on si dide.
Nigbati o si wọ̀ ile, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi i lẽre nikọ̀kọ wipe, Ẽṣe ti awa ko fi le lé e jade?
O si wi fun wọn pe, Irú yi kò le ti ipa ohun kan jade, bikoṣe nipa adura ati àwẹ.
Nwọn si ti ibẹ̀ kuro, nwọn si kọja larin Galili; on kò si fẹ ki ẹnikẹni mọ̀.
Nitori o kọ́ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wi fun wọn pe, A o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ nwọn o si pa a; lẹhin igbati a ba si pa a tan, yio jinde ni ijọ kẹta.
Ṣugbọn ọ̀rọ na kò yé wọn, ẹ̀ru si ba wọn lati bi i lẽre.
O si wá si Kapernaumu: nigbati o si wà ninu ile o bi wọn lẽre, wipe, Kili ohun ti ẹnyin mba ara nyin jiyan si li ọ̀na?
Ṣugbọn nwọn dakẹ: nitori nwọn ti mba ara wọn jiyan pe, tali ẹniti o pọ̀ju.
O si joko, o si pè awọn mejila na, o si wi fun wọn pe, Bi ẹnikẹni ba nfẹ ṣe ẹni iwaju, on na ni yio ṣe ẹni ikẹhin gbogbo wọn, ati iranṣẹ gbogbo wọn.
O si mu ọmọ kekere kan, o fi i sarin wọn; nigbati o si gbé e si apa rẹ̀, o wi fun wọn pe,
Ẹnikẹni ti o ba gbà ọkan ninu iru awọn ọmọ kekere wọnyi li orukọ mi, o gbà mi: ẹnikẹni ti o ba si gbà mi, ki iṣe emi li o gbà, ṣugbọn o gbà ẹniti o rán mi.
Johanu si da a lohùn, o wipe, Olukọni, awa ri ẹnikan nfi orukọ rẹ lé awọn ẹmi èṣu jade, on kò si tọ̀ wa lẹhin: awa si da a lẹkun, nitoriti ko tọ̀ wa lẹhin:
Jesu si wipe, Ẹ máṣe da a lẹkun mọ́: nitori kò si ẹnikan ti yio ṣe iṣẹ agbara li orukọ mi, ti o si le yara sọ ibi si mi.
Nitori ẹniti ko ba kọ oju ija si wa, o wà ni iha tiwa.
Nitori ẹnikẹni ti o ba fi ago omi fun nyin mu li orukọ mi, nitoriti ẹnyin jẹ ti Kristi, lõtọ ni mo wi fun nyin, on kì yio padanù ère rẹ̀ bi o ti wù ki o ri.
Ẹnikẹni ti o ba si mu ki ọkan ninu awọn kekeke wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o sàn fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si sọ ọ sinu omi okun.
Bi ọwọ́ rẹ, ba si mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro: o sàn fun ọ ki o ṣe akewọ lọ si ibi iye, jù ki o li ọwọ mejeji ki o lọ si ọrun apadi, sinu iná ajõku,
Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na kì si ikú.
Bi ẹsẹ rẹ ba si mu ọ kọsè, ke e kuro: o sàn fun ọ ki o ṣe akesẹ lọ si ibi ìye, jù ki o li ẹsẹ mejeji ki a gbé ọ sọ si ọrun apadi, sinu iná ajõku,
Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na ki si ikú.
Bi oju rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade: o sàn fun ọ ki o lọ si ijọba Ọlọrun li olojukan, jù ki o li oju mejeji, ki a gbé ọ sọ sinu iná ọrun apadi,
Nibiti kòkoro wọn ki ikú, ti iná na ki si ikú.
Nitoripe olukukuku li a o fi iná dùn, ati gbogbo ẹbọ li a o si fi iyọ̀ dùn.
Iyọ̀ dara: ṣugbọn bi iyọ̀ ba sọ agbara rẹ̀ nù, kili ẹ o fi mu u dùn? Ẹ ni iyọ̀ ninu ara nyin, ki ẹ si ma wà li alafia lãrin ara nyin.