Awọn Farisi si jade wá, nwọn bẹrẹ si bi i lẽre, nwọn nfẹ àmi lati ọrun wá lọwọ rẹ̀, nwọn ndán a wò.
O si kẹdùn gidigidi ninu ọkàn rẹ̀, o si wipe, Ẽṣe ti iran yi fi nwá àmi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Ko si àmi ti a o fifun iran yi.
O si fi wọn silẹ o si tún bọ sinu ọkọ̀ rekọja lọ si apa ekeji.
Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbagbé lati mu akara lọwọ, nwọn kò si ni jù iṣu akara kan ninu ọkọ̀ pẹlu wọn.
O si kìlọ fun wọn, wipe, Ẹ kiyesara, ki ẹ ma ṣọra nitori iwukara awọn Farisi ati iwukara Herodu.
Nwọn si mba ara wọn ṣe aroye, wipe, Nitoriti awa kò mu akara lọwọ ni.
Nigbati Jesu si mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣàroye pe ẹnyin ko ni akara lọwọ? ẹnyin ko ti ikiyesi titi di isisiyi, ẹ ko si ti iwoye, ẹnyin si li ọkàn lile titi di isisiyi?
Ẹnyin li oju ẹnyin kò si riran? ẹnyin li etí, ẹnyin kò si gbọran? ẹnyin kò si ranti?
Nigbati mo bu iṣu akara marun larin ẹgbẹdọgbọn enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wi fun u pe, Mejila.
Ati nigba iṣu akara meje larin ẹgbaji enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wipe, Meje.
O si wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti kò fi yé nyin?
O si wá si Betsaida; nwọn si mu afọju kan wá sọdọ rẹ̀, nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o fi ọwọ́ kàn a.
O si mu afọju na li ọwọ́, o si fà a jade lọ sẹhin ilu; nigbati o si tutọ́ si i loju, ti o si gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, o bi i lẽre bi o ri ohunkohun.
O si wòke, o si wipe, Mo ri awọn enia dabi igi, nwọn nrìn.
Lẹhin eyini o si tún fi ọwọ́ kàn a loju, o si mu ki o wòke: o si sàn, o si ri gbogbo enia gbangba.
O si rán a pada lọ si ile rẹ̀, wipe, Máṣe lọ si ilu, ki o má si sọ ọ fun ẹnikẹni ni ilu.