Mak 7:31-37

Mak 7:31-37 YBCV

O si tun lọ kuro li àgbegbe Tire on Sidoni, o wá si okun Galili larin àgbegbe Dekapoli. Nwọn si mu enia kan wá sọdọ rẹ̀ ti etí rẹ̀ di, ti o si nkólolo; nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o gbé ọwọ́ rẹ̀ le e. O si mu u kuro larin ijọ enia lọ si apakan, o si tẹ ika rẹ̀ bọ̀ ọ li etí, nigbati o tutọ́, o si fi ọwọ́ tọ́ ọ li ahọn; O si gbé oju soke wo ọrun, o kẹdùn, o si wi fun u pe, Efata, eyini ni, Iwọ ṣí. Lojukanna, etì rẹ̀ si ṣí, okùn ahọn rẹ̀ si tú, o si nsọrọ ketekete. O si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ fun ẹnikẹni: ṣugbọn bi o ti npaṣẹ fun wọn to, bẹ̃ ni nwọn si nkokikí rẹ̀ to; Ẹnu si yà wọn gidigidi rekọja, nwọn wipe, O ṣe ohun gbogbo daradara: o mu aditi gbọran, o si mu ki odi fọhun.

Àwọn fídíò fún Mak 7:31-37

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mak 7:31-37