O si dide ti ibẹ̀ kuro, o si lọ si àgbegbe Tire on Sidoni, o si wọ̀ inu ile kan, ko si fẹ ki ẹnikẹni ki o mọ̀: ṣugbọn on kò le fi ara pamọ́.
Nitori obinrin kan, ẹniti ọmọbinrin rẹ̀ kekere li ẹmi aimọ́ gburo rẹ̀, o wá, o si wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀:
Hellene si li obinrin na, Sirofenikia ni orilẹ-ède rẹ̀; o si bẹ̀ ẹ ki on iba lé ẹmi èṣu na jade lara ọmọbinrin rẹ̀.
Ṣugbọn Jesu wi fun u pe, Jẹ ki a kọ́ fi onjẹ tẹ awọn ọmọ lọrun na: nitoriti ko tọ́ lati mu onjẹ awọn ọmọ, ki a si fi i fun ajá.
O si dahùn o si wi fun u pe, Bẹni Oluwa: ṣugbọn awọn ajá pãpã a ma jẹ ẹrún awọn ọmọ labẹ tabili.
O si wi fun u pe, Nitori ọ̀rọ yi, mã lọ; ẹmi ẹ̀ṣu na ti jade kuro lara ọmọbinrin rẹ.
Nigbati o si pada wá si ile rẹ̀, o ri pe ẹmi èṣu na ti jade, ọmọbinrin rẹ̀ si sùn lori akete.
O si tun lọ kuro li àgbegbe Tire on Sidoni, o wá si okun Galili larin àgbegbe Dekapoli.
Nwọn si mu enia kan wá sọdọ rẹ̀ ti etí rẹ̀ di, ti o si nkólolo; nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o gbé ọwọ́ rẹ̀ le e.
O si mu u kuro larin ijọ enia lọ si apakan, o si tẹ ika rẹ̀ bọ̀ ọ li etí, nigbati o tutọ́, o si fi ọwọ́ tọ́ ọ li ahọn;
O si gbé oju soke wo ọrun, o kẹdùn, o si wi fun u pe, Efata, eyini ni, Iwọ ṣí.
Lojukanna, etì rẹ̀ si ṣí, okùn ahọn rẹ̀ si tú, o si nsọrọ ketekete.
O si paṣẹ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ fun ẹnikẹni: ṣugbọn bi o ti npaṣẹ fun wọn to, bẹ̃ ni nwọn si nkokikí rẹ̀ to;
Ẹnu si yà wọn gidigidi rekọja, nwọn wipe, O ṣe ohun gbogbo daradara: o mu aditi gbọran, o si mu ki odi fọhun.