O si tún bẹ̀rẹ si ikọni leti okun: ọ̀pọ ijọ enia si pejọ sọdọ rẹ̀, tobẹ̃ ti o bọ́ sinu ọkọ̀ kan, o si joko ninu okun; gbogbo awọn enia si wà ni ilẹ leti okun.
O si fi owe kọ́ wọn li ohun pipọ, o si wi fun wọn ninu ẹkọ́ rẹ̀ pe,
Ẹ fi eti silẹ; Wo o, afunrugbin kan jade lọ ifunrugbin;
O si ṣe, bi o ti nfunrugbin, diẹ bọ́ si ẹba ọ̀na, awọn ẹiyẹ si wá, nwọn si ṣà a jẹ.
Diẹ si bọ́ sori ilẹ apata, nibiti kò li erupẹ̀ pipọ; lojukanna o si ti hù jade, nitoriti kò ni ijinlẹ:
Ṣugbọn nigbati õrùn goke, o jóna; nitoriti kò ni gbongbo, o gbẹ.
Diẹ si bọ́ sarin ẹgún, nigbati ẹgún si dàgba soke, o fun u pa, kò si so eso.
Omiran si bọ́ si ilẹ rere, o si so eso, ti o ndagba ti o si npọ̀; o si mu eso jade wá, omiran ọgbọgbọn, omiran ọgọtọta, omiran ọgọrọ̀run.
O si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba li etí lati fi gbọ, ki o gbọ́.
Nigbati o kù on nikan, awọn ti o wà lọdọ rẹ̀ pẹlu awọn mejila bi i lẽre idi owe na.
O si wi fun wọn pe, Ẹnyin li a fifun lati mọ̀ ohun ijinlẹ ijọba Ọlọrun: ṣugbọn fun awọn ti o wà lode, gbogbo ohun wọnyi li a nfi owe sọ fun wọn:
Nitori ni ríri ki nwọn ki o le ri, ki nwọn má si kiyesi; ati ni gbigbọ́ ki nwọn ki o le gbọ́, ki o má si yé wọn; ki nwọn ki o má ba yipada, ki a má ba dari jì wọn.
O si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò mọ̀ owe yi? ẹnyin o ha ti ṣe le mọ̀ owe gbogbo?
Afunrugbin funrugbin ọ̀rọ na.
Awọn wọnyi si ni ti ẹba ọ̀na, nibiti a funrugbin ọ̀rọ na; nigbati nwọn si ti gbọ́, lojukanna Satani wá, o si mu ọ̀rọ na ti a fọn si àiya wọn kuro.
Awọn wọnyi pẹlu si li awọn ti a fun sori ilẹ apata; awọn ẹniti nigbati nwọn ba gbọ́ ọ̀rọ na, lojukanna nwọn a fi ayọ̀ gbà a;
Nwọn kò si ni gbongbo ninu ara wọn, ṣugbọn nwọn a wà fun ìgba diẹ: lẹhinna nigbati wahalà tabi inunibini ba dide nitori ọ̀rọ na, lojukanna nwọn a kọsẹ̀.
Awọn wọnyi li awọn ti a fun sarin ẹgún; awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na,
Aniyan aiye, ati itanjẹ ọrọ̀, ati ifẹkufẹ ohun miran si bọ sinu wọn, nwọn fún ọ̀rọ na pa, bẹ̃li o si jẹ alaileso.
Awọn wọnyi si li eyi ti a fún si ilẹ rere; irú awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na, ti wọn si gbà a, ti wọn si so eso, omiran ọgbọgbọ̀n, omiran ọgọtọta, omiran ọgọrọrun.
O si wi fun wọn pe, A ha gbé fitilà wá lati fi sabẹ òṣuwọn, tabi sabẹ akete, ki a ma si ṣe gbé e kà ori ọpá fitilà?
Nitori kò si ohun ti o pamọ́ bikoṣe ki a le fi i hàn; bẹ̃ni kò si ohun ti o wà ni ikọkọ, bikoṣepe ki o le yọ si gbangba.
Bi ẹnikẹni ba li etí lati fi gbọ́, ki o gbọ́.
O si wi fun wọn pe, Ẹ mã kiyesi ohun ti ẹnyin ngbọ́: òṣuwọn ti ẹnyin ba fi wọ̀n, on li a o fi wọ̀n fun nyin: a o si fi kún u fun nyin.
Nitori ẹniti o ba ni, on li a o fifun: ati ẹniti kò ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi na ti o ni.