Mak 2:1-12

Mak 2:1-12 YBCV

NIGBATI o si tún wọ̀ Kapernaumu lọ lẹhin ijọ melokan; okikí kàn yiká pe, o wà ninu ile. Lojukanna ọ̀pọ enia si pejọ tobẹ̃ ti aye kò si fun wọn mọ, kò si, titi de ẹnu-ọ̀na: o si wasu ọ̀rọ na fun wọn. Nwọn si wá sọdọ rẹ̀, nwọn gbé ẹnikan ti o li ẹ̀gba tọ̀ ọ wá, ẹniti mẹrin gbé. Nigbati nwọn kò si le sunmọ ọ nitori ọ̀pọ enia, nwọn si ṣí orule ile nibiti o gbé wà: nigbati nwọn si da a lu tan, nwọn sọ akete na kalẹ lori eyiti ẹlẹgba na dubulẹ. Nigbati Jesu ri igbagbọ́ wọn, o wi fun ẹlẹgba na pe, Ọmọ, a dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ. Ṣugbọn awọn kan ninu awọn akọwe wà ti nwọn joko nibẹ̀, nwọn si ngbèro li ọkàn wọn, wipe, Ẽṣe ti ọkunrin yi fi sọrọ bayi? o nsọ ọrọ-odi; tali o le dari eṣẹ jìni bikoṣe ẹnikan, aní Ọlọrun? Lojukanna bi Jesu ti woye li ọkàn rẹ̀ pe, nwọn ngbèro bẹ̃ ninu ara wọn, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nrò nkan wọnyi ninu ọkàn nyin? Ewo li o ya jù lati wi fun ẹlẹgba na pe, A dari ẹ̀ṣẹ rẹ jì ọ; tabi lati wipe, Dide, si gbé akete rẹ, ki o si ma rìn? Ṣugbọn ki ẹ le mọ̀ pe, Ọmọ-enia li agbara li aiye lati dari ẹ̀ṣẹ jìni, (o wi fun ẹlẹgba na pe,) Mo wi fun ọ, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã lọ ile rẹ. O si dide lojukanna, o si gbé akete na, o si jade lọ li oju gbogbo wọn; tobẹ̃ ti ẹnu fi yà gbogbo wọn, nwọn si yìn Ọlọrun logo, wipe, Awa ko ri irú eyi rí.

Àwọn fídíò fún Mak 2:1-12

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mak 2:1-12