Mak 15:21-41

Mak 15:21-41 YBCV

Nwọn si fi agbara mu ọkunrin kan, lati rù agbelebu rẹ̀, Simoni ara Kirene, ẹniti nkọja lọ, ti nti igberiko bọ̀, baba Aleksanderu ati Rufu. Nwọn si mu u wá si ibi ti a npè ni Golgota, itumọ eyi ti ijẹ́, Ibi agbari. Nwọn si fi ọti-waini ti a dàpọ mọ ojia fun u lati mu: ṣugbọn on kò gbà a. Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu tan, nwọn si pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gège lori wọn, eyi ti olukuluku iba mú. Ni wakati kẹta ọjọ, on ni nwọn kàn a mọ agbelebu. A si kọwe akọle ọ̀ran ifisùn rẹ̀ si igberi rẹ̀ ỌBA AWỌN JU. Nwọn si kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀; ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi rẹ̀. Iwe-mimọ si ṣẹ, ti o wipe, A si kà a mọ awọn arufin. Awọn ti nrekọja lọ si nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, wipe, A, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, Gbà ara rẹ, ki o si sọkalẹ lati ori agbelebu wá. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu, nwọn nsin i jẹ ninu ara wọn pẹlu awọn akọwe, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; kò le gbà ara rẹ̀. Jẹ ki Kristi, Ọba Israeli, sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, ki awa ki o le ri i, ki a si le gbagbọ́. Awọn ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nkẹgan rẹ̀. Nigbati o di wakati kẹfa, òkunkun si ṣú bò gbogbo ilẹ titi o fi di wakati kẹsan. Ni wakati kẹsan ni Jesu si kigbe soke li ohùn rara, wipe, Eloi, Eloi, lama sabaktani? itumọ eyi ti ijẹ, Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, ẽṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ? Nigbati awọn kan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, Wò o, o npè Elijah. Ẹnikan si sare, o fi sponge bọ ọti kikan, o fi le ori ọpá iyè, o fifun u mu, wipe, Ẹ jọwọ rẹ̀ si; ẹ jẹ ki a ma wò bi Elijah yio wá gbé e sọkalẹ. Jesu si kigbe soke li ohùn rara, o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ. Aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ. Nigbati balogun ọrún, ti o duro niha ọdọ rẹ̀ ri ti o kigbe soke bayi, ti o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ, o wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li ọkunrin yi iṣe. Awọn obinrin pẹlu si wà li òkere nwọn nwò: ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu kekere, ati ti Jose ati Salome; (Awọn ẹniti, nigbati o wà ni Galili, ti nwọn ntọ̀ ọ lẹhin, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u;) ati ọ̀pọ obinrin miran pẹlu, ti o ba a goke wá si Jerusalemu.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa