Nwọn si fi aṣọ elesè àluko wọ̀ ọ, nwọn hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori; Nwọn si bẹ̀rẹ si ikí i, wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! Nwọn si fi ọpá iye lù u lori, nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si foribalẹ fun u. Nigbati nwọn si fi i ṣẹ̀sin tan, nwọn si bọ́ aṣọ elesè àluko na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si mu u jade lọ lati kàn a mọ agbelebu. Nwọn si fi agbara mu ọkunrin kan, lati rù agbelebu rẹ̀, Simoni ara Kirene, ẹniti nkọja lọ, ti nti igberiko bọ̀, baba Aleksanderu ati Rufu. Nwọn si mu u wá si ibi ti a npè ni Golgota, itumọ eyi ti ijẹ́, Ibi agbari.
Kà Mak 15
Feti si Mak 15
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mak 15:17-22
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò