Mak 15:16-32

Mak 15:16-32 YBCV

Awọn ọmọ-ogun si fà a jade lọ sinu gbọ̀ngan, ti a npè ni Pretorioni; nwọn si pè gbogbo ẹgbẹ awọn ọmọ-ogun jọ. Nwọn si fi aṣọ elesè àluko wọ̀ ọ, nwọn hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori; Nwọn si bẹ̀rẹ si ikí i, wipe, Kabiyesi, Ọba awọn Ju! Nwọn si fi ọpá iye lù u lori, nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si foribalẹ fun u. Nigbati nwọn si fi i ṣẹ̀sin tan, nwọn si bọ́ aṣọ elesè àluko na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si mu u jade lọ lati kàn a mọ agbelebu. Nwọn si fi agbara mu ọkunrin kan, lati rù agbelebu rẹ̀, Simoni ara Kirene, ẹniti nkọja lọ, ti nti igberiko bọ̀, baba Aleksanderu ati Rufu. Nwọn si mu u wá si ibi ti a npè ni Golgota, itumọ eyi ti ijẹ́, Ibi agbari. Nwọn si fi ọti-waini ti a dàpọ mọ ojia fun u lati mu: ṣugbọn on kò gbà a. Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu tan, nwọn si pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gège lori wọn, eyi ti olukuluku iba mú. Ni wakati kẹta ọjọ, on ni nwọn kàn a mọ agbelebu. A si kọwe akọle ọ̀ran ifisùn rẹ̀ si igberi rẹ̀ ỌBA AWỌN JU. Nwọn si kàn awọn olè meji mọ agbelebu pẹlu rẹ̀; ọkan li ọwọ́ ọtún, ati ekeji li ọwọ́ òsi rẹ̀. Iwe-mimọ si ṣẹ, ti o wipe, A si kà a mọ awọn arufin. Awọn ti nrekọja lọ si nfi i ṣe ẹlẹyà, nwọn si nmì ori wọn, wipe, A, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, Gbà ara rẹ, ki o si sọkalẹ lati ori agbelebu wá. Gẹgẹ bẹ̃li awọn olori alufa pẹlu, nwọn nsin i jẹ ninu ara wọn pẹlu awọn akọwe, wipe, O gbà awọn ẹlomiran là; kò le gbà ara rẹ̀. Jẹ ki Kristi, Ọba Israeli, sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, ki awa ki o le ri i, ki a si le gbagbọ́. Awọn ti a kàn mọ agbelebu pẹlu rẹ̀ si nkẹgan rẹ̀.