Mak 14:53-72

Mak 14:53-72 YBCV

Nwọn si mu Jesu lọ ṣọdọ olori alufa: gbogbo awọn olori alufa, ati awọn agbagba, ati awọn akọwe si pejọ pẹlu rẹ̀. Peteru si tọ̀ ọ lẹhin li òkere wọ̀ inu ile, titi fi de agbala olori alufa; o si bá awọn ọmọ-ọdọ joko, o si nyána. Awọn olori alufa ati gbogbo ajọ ìgbimọ nwá ẹlẹri si Jesu lati pa a; nwọn kò si ri ohun kan. Nitoripe ọ̀pọlọpọ li o jẹri eke si i, ṣugbọn ohùn awọn ẹlẹri na kò ṣọkan. Awọn kan si dide, nwọn njẹri eke si i, wipe, Awa gbọ́ o wipe, Emi ó wó tẹmpili yi ti a fi ọwọ́ ṣe, niwọn ijọ́ mẹta emi o si kọ́ omiran ti a kò fi ọwọ́ ṣe. Ati ninu eyi na pẹlu, ohùn wọn kò ṣọkan. Olori alufa si dide duro larin, o si bi Jesu lẽre, wipe, Iwọ kò dahùn kan? kili eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ? Ṣugbọn Jesu dakẹ, ko si dahùn ohun kan. Olori alufa si tun bi i lẽre, o wi fun u pe, Iwọ ni Kristi na, Ọmọ Olubukun nì? Jesu si wipe, Emi ni: ẹnyin o si ri Ọmọ-enia joko li ọwọ́ ọtún agbara, yio si ma ti inu awọsanma ọrun wá. Nigbana li olori alufa fà aṣọ rẹ̀ ya, o wipe, Ẹlẹri kili a si nwá? Ẹnyin gbọ́ ọrọ-odi na: ẹnyin ti rò o si? Gbogbo wọn si da a lẹbi pe, o jẹbi ikú. Awọn miran si bẹ̀rẹ si itutọ́ si i lara, ati si ibò o loju, ati si ikàn a lẹṣẹ́, nwọn si wi fun u pe, Sọtẹlẹ: awọn onṣẹ si nfi atẹlẹ ọwọ́ wọn gbá a loju. Bi Peteru si ti wà ni isalẹ li ãfin, ọkan ninu awọn ọmọbinrin olori alufa wá: Nigbati o si ri ti Peteru nyána, o wò o, o si wipe, Iwọ pẹlu ti wà pẹlu Jesu ti Nasareti. Ṣugbọn o sẹ́, wipe, Emi ko mọ̀, oyé ohun ti iwọ nwi kò tilẹ yé mi. O si jade lọ si iloro; akukọ si kọ. Ọmọbinrin na si tún ri i, o si bẹ̀rẹ si iwi fun awọn ti o duro nibẹ̀ pe, Ọkan ninu wọn ni eyi. O si tún sẹ́. O si pẹ diẹ, awọn ti o duro nibẹ̀ tún wi fun Peteru pe, Lõtọ ni, ọkan ninu wọn ni iwọ iṣe: nitoripe ara Galili ni iwọ, ède rẹ si jọ bẹ̃. Ṣugbọn o bẹ̀rẹ si iré ati si ibura, wipe, Emi ko mọ̀ ọkunrin yi ẹniti ẹnyin nwi. Lojukanna akukọ si kọ lẹrinkeji. Peteru si ranti ọrọ ti Jesu wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ lẹrinmeji, iwo o sẹ́ mi lẹrinmẹta. Nigbati o si rò o, o sọkun.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mak 14:53-72

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa