Mak 14:53-72

Mak 14:53-72 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nwọn si mu Jesu lọ ṣọdọ olori alufa: gbogbo awọn olori alufa, ati awọn agbagba, ati awọn akọwe si pejọ pẹlu rẹ̀. Peteru si tọ̀ ọ lẹhin li òkere wọ̀ inu ile, titi fi de agbala olori alufa; o si bá awọn ọmọ-ọdọ joko, o si nyána. Awọn olori alufa ati gbogbo ajọ ìgbimọ nwá ẹlẹri si Jesu lati pa a; nwọn kò si ri ohun kan. Nitoripe ọ̀pọlọpọ li o jẹri eke si i, ṣugbọn ohùn awọn ẹlẹri na kò ṣọkan. Awọn kan si dide, nwọn njẹri eke si i, wipe, Awa gbọ́ o wipe, Emi ó wó tẹmpili yi ti a fi ọwọ́ ṣe, niwọn ijọ́ mẹta emi o si kọ́ omiran ti a kò fi ọwọ́ ṣe. Ati ninu eyi na pẹlu, ohùn wọn kò ṣọkan. Olori alufa si dide duro larin, o si bi Jesu lẽre, wipe, Iwọ kò dahùn kan? kili eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ? Ṣugbọn Jesu dakẹ, ko si dahùn ohun kan. Olori alufa si tun bi i lẽre, o wi fun u pe, Iwọ ni Kristi na, Ọmọ Olubukun nì? Jesu si wipe, Emi ni: ẹnyin o si ri Ọmọ-enia joko li ọwọ́ ọtún agbara, yio si ma ti inu awọsanma ọrun wá. Nigbana li olori alufa fà aṣọ rẹ̀ ya, o wipe, Ẹlẹri kili a si nwá? Ẹnyin gbọ́ ọrọ-odi na: ẹnyin ti rò o si? Gbogbo wọn si da a lẹbi pe, o jẹbi ikú. Awọn miran si bẹ̀rẹ si itutọ́ si i lara, ati si ibò o loju, ati si ikàn a lẹṣẹ́, nwọn si wi fun u pe, Sọtẹlẹ: awọn onṣẹ si nfi atẹlẹ ọwọ́ wọn gbá a loju. Bi Peteru si ti wà ni isalẹ li ãfin, ọkan ninu awọn ọmọbinrin olori alufa wá: Nigbati o si ri ti Peteru nyána, o wò o, o si wipe, Iwọ pẹlu ti wà pẹlu Jesu ti Nasareti. Ṣugbọn o sẹ́, wipe, Emi ko mọ̀, oyé ohun ti iwọ nwi kò tilẹ yé mi. O si jade lọ si iloro; akukọ si kọ. Ọmọbinrin na si tún ri i, o si bẹ̀rẹ si iwi fun awọn ti o duro nibẹ̀ pe, Ọkan ninu wọn ni eyi. O si tún sẹ́. O si pẹ diẹ, awọn ti o duro nibẹ̀ tún wi fun Peteru pe, Lõtọ ni, ọkan ninu wọn ni iwọ iṣe: nitoripe ara Galili ni iwọ, ède rẹ si jọ bẹ̃. Ṣugbọn o bẹ̀rẹ si iré ati si ibura, wipe, Emi ko mọ̀ ọkunrin yi ẹniti ẹnyin nwi. Lojukanna akukọ si kọ lẹrinkeji. Peteru si ranti ọrọ ti Jesu wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ lẹrinmeji, iwo o sẹ́ mi lẹrinmẹta. Nigbati o si rò o, o sọkun.

Mak 14:53-72 Yoruba Bible (YCE)

Wọ́n mú Jesu lọ sí ọ̀dọ̀ Olórí Alufaa, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ati àwọn amòfin wá péjọ sibẹ. Peteru wà ní òkèèrè, ó ń tẹ̀lé e títí ó fi wọ agbo-ilé Olórí Alufaa, ó bá jókòó pẹlu àwọn iranṣẹ, wọ́n jọ ń yá iná. Àwọn olórí alufaa ati gbogbo Ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí tí ó lòdì sí Jesu, kí wọ́n baà lè pa á, ṣugbọn wọn kò rí. Nítorí ọpọlọpọ ní ń jẹ́rìí èké sí i, ṣugbọn ẹ̀rí wọn kò bá ara wọn mu. Àwọn kan wá dìde, wọ́n ń jẹ́rìí èké sí i pé, “A gbọ́ nígbà tí ó ń wí pé, ‘Èmi yóo wó Tẹmpili tí eniyan kọ́ yìí, láàrin ọjọ́ mẹta, èmi óo gbé òmíràn dìde tí eniyan kò kọ́.’ ” Sibẹ ẹ̀rí wọn kò bá ara wọn mu. Nígbà náà ni Olórí Alufaa dìde láàrin wọn, ó bi Jesu pé, “Ìwọ kò fèsì rárá?” Ṣugbọn ó sá dákẹ́ ni, kò fèsì kankan. Olórí Alufaa tún bi í pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún?” Jesu dáhùn pé, “Èmi ni. Ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.” Olórí Alufaa bá fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó ní, “Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá? Ẹ ti gbọ́ tí ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun! Kí ni ẹ wí?” Gbogbo wọn bá dá a lẹ́bi, wọ́n ní ikú ni ó tọ́ sí i. Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́ sí i lára. Wọ́n fi aṣọ bò ó lójú, wọ́n wá ń sọ ọ́ ní ẹ̀ṣẹ́. Wọ́n sọ fún un pé, “Sọ ẹni tí ó lù ọ́ fún wa, wolii!” Àwọn iranṣẹ wá ń gbá a létí bí wọn ti ń mú un lọ sí àtìmọ́lé. Nígbà tí Peteru wà ní ìsàlẹ̀ ní agbo-ilé, ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin Olórí Alufaa dé. Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ń yáná, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.” Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “Èmi kò mọ̀... Ohun tí ò ń sọ kò yé mi rárá!” Ó wá jáde lọ sí apá ẹnu ọ̀nà agbo-ilé. Bẹ́ẹ̀ ni àkùkọ kan bá kọ. Iranṣẹbinrin náà tún bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn tí ó dúró pé, “Ọkunrin yìí wà ninu wọn!” Ṣugbọn ó tún sẹ́. Nígbà tí ó ṣe díẹ̀ síi àwọn tí ó dúró sọ fún Peteru pé, “Dájúdájú, o wà ninu wọn nítorí ará Galili ni ọ́.” Peteru bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣépè, ó bá ń búra pé, “N kò mọ ọkunrin tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí.” Lẹsẹkẹsẹ, àkùkọ kọ ní ẹẹkeji. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta!” Orí Peteru wú, ó bá bú sẹ́kún.

Mak 14:53-72 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Wọ́n mú Jesu lọ sí ilé olórí àlùfáà, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù àti àwọn olùkọ́ òfin péjọ síbẹ̀. Peteru tẹ̀lé Jesu lókèèrè, ó sì yọ́ wọ inú àgbàlá olórí àlùfáà, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ó ń yáná. Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ń wá ẹni tí yóò jẹ́rìí èké sí Jesu, èyí tí ó jọjú dáradára láti lè dájọ́ ikú fún un. Ṣùgbọ́n wọn kò rí. Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí wọ́n ní kò bá ara wọn mu. Níkẹyìn àwọn kan dìde, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́rìí èké sí i, wọ́n ní “A gbọ́ tí ó wí pé ‘Èmi yóò wó tẹmpili tí ẹ fi ọwọ́ kọ́ yìí, nígbà tí yóò bá sì fi di ọjọ́ kẹta, èmi yóò kọ́ òmíràn ti a kò fi ọwọ́ ènìyàn kọ́.’ ” Síbẹ̀, ẹ̀rí i wọn kò dọ́gba. Nígbà náà ni àlùfáà àgbà dìde, ó bọ́ síwájú. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi Jesu léèrè, ó ní, “Ṣé o kò ní fèsì sí ẹ̀sùn tí wọ́n fi sùn ọ? Kí ni ìwọ gan an ní sọ fúnrarẹ̀?” Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́. Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ní, “Ṣé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún un nì?” Jesu wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni: Ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára. Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọsánmọ̀ ojú ọ̀run.” Nígbà náà ni Olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “Kí ló kù tì a ń wá? Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? Ẹ̀yin fúnrayín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì tí ó sọ. Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe?” Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ó jẹ̀bi ikú.” Àwọn kan sì bẹ̀rẹ̀ sí í tu itọ́ sí i lára. Wọ́n dì í lójú. Wọ́n ń kàn án lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Sọtẹ́lẹ̀!” Àwọn olùṣọ́ sì ń fi àtẹ́lẹwọ́ wọn gbá a lójú. Ní àkókò yìí Peteru wà ní ìsàlẹ̀ inú àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Nínú àgbàlá yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́bìnrin àlùfáà àgbà kíyèsi í tí Peteru ń yáná. Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ti yáná, Ó tẹjúmọ́ ọn. Ó sì sọ gbangba pé, “Ìwọ pàápàá wà pẹ̀lú Jesu ara Nasareti.” Ṣùgbọ́n Peteru sẹ́, ó ni, “N kò mọ Jesu náà rí; ohun tí ó ń sọ yìí kò tilẹ̀ yé mi.” Peteru sì jáde lọ sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ilé ìgbẹ́jọ́. Àkùkọ sì kọ. Ọmọbìnrin náà sì tún rí Peteru. Ó sì tún bẹ̀rẹ̀ sí wí fún àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀. Ó ní, “Ọkùnrin yìí gan an jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.” Ṣùgbọ́n Peteru tún sẹ́. Nígbà tí ó sí túnṣe díẹ̀ sí i, àwọn tí wọ́n dúró lẹ́gbẹ́ Peteru wá wí fún un pé, “Lóòótọ́ ni, ọ̀kan ní ara wọn ni ìwọ í ṣe. Nítorí ará Galili ni ìwọ, èdè rẹ sì jọ bẹ́ẹ̀.” Nígbà náà ni Peteru bẹ̀rẹ̀ sí í sẹ́ ó sì ń búra, ó ni, “N kò mọ ẹni ti ẹ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yí rí!” Lójúkan náà tí àkùkọ yìí kọ lẹ́ẹ̀kejì Peteru rántí ọ̀rọ̀ Jesu fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ lẹ́ẹ̀méjì, ìwọ yóò sẹ́ mí nígbà mẹ́ta.” Ó sì rẹ̀ ẹ́ láti inú ọkàn wá, ó sì sọkún.