Mak 14:32-72

Mak 14:32-72 YBCV

Nwọn si wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane: o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi, nigbati mo ba lọ igbadura. O si mu Peteru ati Jakọbu ati Johanu pẹlu rẹ̀, ẹnu si bẹrẹ si yà a gidigidi, o si bẹré si rẹ̀wẹsi. O si wi fun wọn pẹ, Ọkàn mi nkãnu gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihin, ki ẹ si mã ṣọna. O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ, o si gbadura pe, bi o ba le ṣe, ki wakati na le kọja kuro lori rẹ̀. O si wipe, Abba, Baba, ṣiṣe li ohun gbogbo fun ọ; mú ago yi kuro lori mi: ṣugbọn kì iṣe eyiti emi fẹ, bikoṣe eyiti iwọ fẹ, O si wá, o ba wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Simoni, iwọ nsùn? iwọ kò le ṣọna ni wakati kan? Ẹ mã ṣọna, kì ẹ si mã gbadura, ki ẹ má ba bọ́ sinu idẹwò. Lõtọ li ẹmí nfẹ, ṣugbọn o ṣe ailera fun ara. O si tún pada lọ, o si gbadura, o nsọ ọ̀rọ kanna. Nigbati o si pada wá, o tún bá wọn, nwọn nsùn, nitoriti oju wọn kún fun orun, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀ èsi ti nwọn iba fifun u. O si wá li ẹrinkẹta, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã sùn wayi, ki ẹ si mã simi: o to bẹ̃, wakati na de; wo o, a fi Ọmọ-enia le awọn ẹlẹṣẹ lọwọ. Ẹ dide, ki a ma lọ; wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi. Lojukanna, bi o si ti nsọ lọwọ, Judasi de, ọkan ninu awọn mejila, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà, pẹlu ọgọ, lati ọdọ olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn agbagba wá. Ẹniti o si fi i hàn ti fi àmi fun wọn, wipe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu kò li ẹnu, on na ni; ẹ mu u, ki ẹ si ma fà a lọ li alafia. Nigbati o de, o tọ̀ ọ lọ gan, o wipe, Olukọni, olukọni! o si fi ẹnu kò o li ẹnu. Nwọn si gbé ọwọ́ wọn le e, nwọn si mu u. Ṣugbọn ọkan ninu awọn ti o duro nibẹ̀ fà idà yọ, o si sá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí rẹ̀ kuro. Jesu si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi li ẹnyin jade tọ̀ wá bi olè, ti ẹnyin ti idà ati ọgọ lati mu? Li ojojumọ li emi wà pẹlu nyin ni tẹmpili, ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si mu mi: ṣugbọn iwe-mimọ kò le ṣe alaiṣẹ. Gbogbo wọn si fi i silẹ, nwọn si sá lọ. Ọmọkunrin kan si ntọ̀ ọ lẹhin, ti o fi aṣọ ọgbọ bò ìhoho rẹ̀; awọn ọmọ-ogun si gbá a mu: O si jọwọ aṣọ ọgbọ na lọwọ, o si sá kuro lọdọ wọn nihoho. Nwọn si mu Jesu lọ ṣọdọ olori alufa: gbogbo awọn olori alufa, ati awọn agbagba, ati awọn akọwe si pejọ pẹlu rẹ̀. Peteru si tọ̀ ọ lẹhin li òkere wọ̀ inu ile, titi fi de agbala olori alufa; o si bá awọn ọmọ-ọdọ joko, o si nyána. Awọn olori alufa ati gbogbo ajọ ìgbimọ nwá ẹlẹri si Jesu lati pa a; nwọn kò si ri ohun kan. Nitoripe ọ̀pọlọpọ li o jẹri eke si i, ṣugbọn ohùn awọn ẹlẹri na kò ṣọkan. Awọn kan si dide, nwọn njẹri eke si i, wipe, Awa gbọ́ o wipe, Emi ó wó tẹmpili yi ti a fi ọwọ́ ṣe, niwọn ijọ́ mẹta emi o si kọ́ omiran ti a kò fi ọwọ́ ṣe. Ati ninu eyi na pẹlu, ohùn wọn kò ṣọkan. Olori alufa si dide duro larin, o si bi Jesu lẽre, wipe, Iwọ kò dahùn kan? kili eyi ti awọn wọnyi njẹri si ọ? Ṣugbọn Jesu dakẹ, ko si dahùn ohun kan. Olori alufa si tun bi i lẽre, o wi fun u pe, Iwọ ni Kristi na, Ọmọ Olubukun nì? Jesu si wipe, Emi ni: ẹnyin o si ri Ọmọ-enia joko li ọwọ́ ọtún agbara, yio si ma ti inu awọsanma ọrun wá. Nigbana li olori alufa fà aṣọ rẹ̀ ya, o wipe, Ẹlẹri kili a si nwá? Ẹnyin gbọ́ ọrọ-odi na: ẹnyin ti rò o si? Gbogbo wọn si da a lẹbi pe, o jẹbi ikú. Awọn miran si bẹ̀rẹ si itutọ́ si i lara, ati si ibò o loju, ati si ikàn a lẹṣẹ́, nwọn si wi fun u pe, Sọtẹlẹ: awọn onṣẹ si nfi atẹlẹ ọwọ́ wọn gbá a loju. Bi Peteru si ti wà ni isalẹ li ãfin, ọkan ninu awọn ọmọbinrin olori alufa wá: Nigbati o si ri ti Peteru nyána, o wò o, o si wipe, Iwọ pẹlu ti wà pẹlu Jesu ti Nasareti. Ṣugbọn o sẹ́, wipe, Emi ko mọ̀, oyé ohun ti iwọ nwi kò tilẹ yé mi. O si jade lọ si iloro; akukọ si kọ. Ọmọbinrin na si tún ri i, o si bẹ̀rẹ si iwi fun awọn ti o duro nibẹ̀ pe, Ọkan ninu wọn ni eyi. O si tún sẹ́. O si pẹ diẹ, awọn ti o duro nibẹ̀ tún wi fun Peteru pe, Lõtọ ni, ọkan ninu wọn ni iwọ iṣe: nitoripe ara Galili ni iwọ, ède rẹ si jọ bẹ̃. Ṣugbọn o bẹ̀rẹ si iré ati si ibura, wipe, Emi ko mọ̀ ọkunrin yi ẹniti ẹnyin nwi. Lojukanna akukọ si kọ lẹrinkeji. Peteru si ranti ọrọ ti Jesu wi fun u pe, Ki akukọ ki o to kọ lẹrinmeji, iwo o sẹ́ mi lẹrinmẹta. Nigbati o si rò o, o sọkun.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ