Nwọn si wà li ọ̀na nwọn ngoke lọ si Jerusalemu; Jesu si nlọ niwaju wọn: ẹnu si yà wọn; bi nwọn si ti ntọ̀ ọ lẹhin, ẹ̀ru ba wọn. O si tun mu awọn mejila, o bẹ̀rẹ si isọ gbogbo ohun ti a o ṣe si i fun wọn,
Wipe, Sá wo o, awa ngoke lọ si Jerusalemu, a o si fi Ọmọ-enia le awọn olori alufa, ati awọn akọwe lọwọ; nwọn o si da a lẹbi ikú, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ:
Nwọn o si fi i ṣe ẹlẹyà, nwọn o si nà a, nwọn o si tutọ́ si i lara, nwọn o si pa a: ni ijọ kẹta yio si jinde.
Jakọbu ati Johanu awọn ọmọ Sebede si wá sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa nfẹ ki iwọ ki o ṣe ohunkohun ti awa ba bere lọwọ rẹ fun wa.
O si bi wọn lẽre pe, Kili ẹnyin nfẹ ki emi ki o ṣe fun nyin?
Nwọn si wi fun u pe, Fifun wa ki awa ki o le joko, ọkan li ọwọ́ ọtun rẹ, ati ọkan li ọwọ́ òsi rẹ, ninu ogo rẹ.
Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ko mọ̀ ohun ti ẹnyin mbère: ẹnyin le mu ago ti emi mu? tabi ki a fi baptismu ti a fi baptisi mi baptisi nyin?
Nwọn si wi fun u pe, Awa le ṣe e. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin ó mu ago ti emi mu; ati baptismu ti a o fi baptisi mi li a o fi baptisi nyin:
Ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún mi ati li ọwọ́ òsi mi ki iṣe ti emi lati fi funni: bikoṣe fun awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ.
Nigbati awọn mẹwa iyokù gbọ́, nwọn bẹ̀re si ibinu si Jakọbu ati Johanu.
Ṣugbọn Jesu pè wọn sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ pe, awọn ti a nkà si olori awọn Keferi, a ma lò ipá lori wọn: ati awọn ẹni-nla wọn a ma fi ọlá tẹri wọn ba.
Ṣugbọn kì yio ri bẹ̃ lãrin nyin: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba fẹ tobi lãrin nyin, on ni yio ṣe iranṣẹ nyin:
Ati ẹnikẹni ninu nyin ti o ba fẹ ṣe olori, on ni yio ṣe ọmọ-ọdọ gbogbo nyin.
Nitori Ọmọ-enia tikalarẹ̀ kò ti wá ki a ba mã ṣe iranṣẹ fun, bikoṣe lati mã ṣe iranṣẹ funni, ati lati fi ẹmi rẹ̀ ṣe irapada fun ọ̀pọlọpọ enia.
Nwọn si wá si Jeriko: bi o si ti njade kuro ni Jeriko pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati ọ̀pọ awọn enia, Bartimeu afọju, ọmọ Timeu, joko lẹba ọ̀na, o nṣagbe.
Nigbati o gbọ́ pe, Jesu ti Nasareti ni, o bẹ̀rẹ si ikigbe lohùn rara, wipe, Jesu, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.
Ọpọlọpọ si ba a wipe, ki o pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣugbọn on si kigbe si i jù bẹ̃ lọ pe, Iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun mi.
Jesu si dẹsẹ duro, o si paṣẹ pe ki a pè e wá. Nwọn si pè afọju na, nwọn wi fun u pe, Tùjuka, dide; o npè ọ.
O si bọ ẹ̀wu rẹ́ sọnù, o dide, o si tọ̀ Jesu wá.
Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe fun ọ? Afọju na si wi fun u pe, Rabboni, ki emi ki o le riran.
Jesu si wi fun u pe, Mã lọ; igbagbọ́ rẹ mu ọ larada. Lojukanna, o si riran, o si tọ̀ Jesu lẹhin li ọ̀na.