O si dide kuro nibẹ̀, o si wá si ẹkùn Judea niha oke odò Jordani: awọn enia si tún tọ̀ ọ wá; bi iṣe rẹ̀ ti ri, o si tún nkọ́ wọn.
Awọn Farisi si tọ̀ ọ wá, nwọn ndán a wò, nwọn si bi i lẽre, wipe, O tọ́ fun ọkunrin ki o fi aya rẹ̀ silẹ?
O si dahùn o si wi fun wọn pe, Aṣẹ kini Mose pa fun nyin?
Nwọn si wipe, Mose yọda fun wa lati kọ iwe ikọsilẹ fun u, ki a si fi i silẹ.
Jesu si da wọn lohùn, o si wi fun wọn pe, Nitori lile àiya nyin li o ṣe kọ irú ofin yi fun nyin.
Ṣugbọn lati igba ti aiye ti ṣẹ, Ọlọrun da wọn ti akọ ti abo.
Nitori eyi li ọkunrin yio ṣe fi baba ati iya rẹ̀ silẹ ti yio si faramọ aya rẹ̀;
Awọn mejeji a si di ara kan: nitorina nwọn kì iṣe meji mọ́, bikoṣe ara kan.
Nitorina ohun ti Ọlọrun ba so ṣọkan, ki enia ki o máṣe yà wọn.
Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si tun bi i lẽre ọ̀ran kanna ninu ile.
O si wi fun wọn pe, Ẹnikẹni ti o ba fi aya rẹ̀ silẹ, ti o ba si gbé omiran ni iyawo, o ṣe panṣaga si i.
Bi obinrin kan ba si fi ọkọ rẹ̀ silẹ, ti a ba si gbé e ni iyawo fun ẹlomiran, o ṣe panṣaga.
Nwọn si gbé awọn ọmọ-ọwọ tọ̀ ọ wá, ki o le fi ọwọ́ tọ́ wọn: awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ba awọn ti o gbé wọn wá wi.
Ṣugbọn nigbati Jesu ri i, inu bi i, o si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki awọn ọmọ kekere ki o wá sọdọ mi, ẹ má si ṣe da wọn lẹkun: nitoriti irú wọn ni ijọba Ọlọrun.
Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti kò ba gbà ijọba Ọlọrun bi ọmọ kekere, kì yio le wọ̀ inu rẹ̀ bi o ti wù o ri.
O si gbé wọn si apa rẹ̀, o gbé ọwọ́ rẹ̀ le wọn, o si sure fun wọn.
Bi o si ti njade bọ̀ si ọ̀na, ẹnikan nsare tọ̀ ọ wá, o si kunlẹ fun u, o bi i lẽre, wipe, Olukọni rere, kili emi o ṣe ti emi o fi le jogún ìye ainipẹkun?
Jesu si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ fi npè mi li ẹni rere? Ẹni rere kan ko si bikoṣe ẹnikan, eyini li Ọlọrun.
Iwọ sá mọ̀ ofin: Máṣe panṣaga, Máṣe pania, Máṣe jale, Máṣe jẹri eke, Máṣe rẹ-ni-jẹ, Bọwọ fun baba on iya rẹ.
O si dahùn o si wi fun u pe, Olukọni, gbogbo nkan wọnyi li emi ti nkiyesi lati igba ewe mi wá.
Nigbana ni Jesu sì wò o, o fẹràn rẹ̀, o si wi fun u pe, Ohun kan li o kù ọ kù: lọ tà ohunkohun ti o ni ki o si fifun awọn talakà, iwọ ó si ni iṣura li ọrun: si wá, gbé agbelebu, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.
Inu rẹ̀ si bajẹ si ọ̀rọ̀ na, o si jade lọ ni ibinujẹ: nitoriti o li ọrọ̀ pipọ.
Jesu si wò yiká, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun!
Ẹnu si yà awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ọ̀rọ rẹ̀. Ṣugbọn Jesu si tun dahùn wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọ, yio ti ṣoro to fun awọn ti o gbẹkẹle ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun!
O rọrun fun ibakasiẹ lati wọ̀ oju abẹrẹ jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ.
Ẹnu si yà wọn rekọja, nwọn si mba ara wọn sọ wipe, Njẹ tali o ha le là?
Jesu si wò wọn o wipe, Enia li eyi ko le ṣe iṣe fun, ṣugbọn ki iṣe fun Ọlọrun: nitori ohun gbogbo ni ṣiṣe fun Ọlọrun.
Nigbana ni Peteru bẹ̀rẹ si iwi fun u pe, Wo o, awa ti fi gbogbo nkan silẹ awa si ti tọ̀ ọ lẹhin.
Jesu si dahùn, o wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si ẹniti o fi ile silẹ, tabi arakunrin, tabi arabinrin, tabi baba, tabi iya, tabi aya, tabi ọmọ, tabi ilẹ, nitori mi, ati nitori ihinrere,
Ṣugbọn nisisiyi li aiye yi on o si gbà ọgọrọrun, ile, ati arakunrin, ati arabinrin, ati iya, ati ọmọ, ati ilẹ, pẹlu inunibini, ati li aiye ti mbọ̀ ìye ainipẹkun;
Ṣugbọn ọ̀pọ awọn ti o ṣiwaju ni yio kẹhin; awọn ti o kẹhin ni yio si ṣiwaju.