MAKU 10:1-31

MAKU 10:1-31 YCE

Nígbà tí Jesu dìde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Judia, ó rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Ọpọlọpọ àwọn eniyan tún lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó tún ń kọ́ wọn. Àwọn Farisi bá jáde wá, wọ́n ń bi í bí ó bá tọ́ kí ọkunrin kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀. Wọ́n fi ìbéèrè yìí dán an wò ni. Ó dá wọn lóhùn pé, “Kí ni Mose pa láṣẹ fun yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Mose yọ̀ǹda pé kí ọkọ kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ fún iyawo rẹ̀, kí ó sì kọ̀ ọ́.” Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Nítorí oríkunkun yín ni Mose fi kọ òfin yìí. Láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé, takọ-tabo ni Ọlọrun dá wọn. Nítorí èyí ni ọkunrin yóo ṣe fi baba ati ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóo wá fi ara mọ́ iyawo rẹ̀; àwọn mejeeji yóo wá di ọ̀kan. Wọn kì í tún ṣe ẹni meji mọ́ bíkòṣe ọ̀kan. Nítorí náà ohun tí Ọlọrun bá ti so pọ̀, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà á.” Nígbà tí wọ́n pada wọ inú ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi í nípa ọ̀rọ̀ náà. Ó bá wí fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ iyawo rẹ̀ sílẹ̀, tí ó gbé ẹlòmíràn ní iyawo, ó ṣe àgbèrè sí iyawo rẹ̀ àkọ́kọ́. Bí ó bá sì jẹ́ pé obinrin ni ó kọ ọkọ rẹ̀, tí ó fẹ́ ọkọ mìíràn, òun náà ṣe àgbèrè.” Àwọn kan gbé àwọn ọmọ kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kí ó lè fi ọwọ́ kàn wọ́n. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá àwọn tí ó gbé wọn wá wí. Nígbà tí Jesu rí i inú bí i: ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí ti irú wọn ni ìjọba Ọlọrun. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ìjọba Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ọmọde, kò ní wọ ìjọba ọ̀run.” Nígbà náà ni Jesu gbé àwọn ọmọde náà lọ́wọ́, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì súre fún wọn. Nígbà tí Jesu jáde, bí ó ti ń lọ lọ́nà, ọkunrin kan sáré tọ̀ ọ́ lọ, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bi í pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?” Ṣugbọn Jesu wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan, àfi Ọlọrun nìkan. Ṣé o mọ àwọn òfin: má paniyan, má ṣe àgbèrè, má jalè, má jẹ́rìí èké, má rẹ́nijẹ, bọ̀wọ̀ fún baba ati ìyá rẹ?” Ọkunrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, láti ìgbà tí mo ti wà ní ọdọmọkunrin ni mo ti ń pa gbogbo nǹkan wọnyi mọ́.” Jesu wá tẹjú mọ́ ọn, ó fi tìfẹ́tìfẹ́ wò ó, ó wí fún un pé, “Nǹkankan ló kù kí o ṣe: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn aláìní, o óo wá ní ọrọ̀ ní ọ̀run; lẹ́yìn náà wá, kí o máa tẹ̀lé mi.” Ṣugbọn ojú ọkunrin náà fàro nígbà tí ó gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó bá jáde lọ pẹlu ìbànújẹ́, nítorí pé ọrọ̀ tí ó ní pọ̀. Jesu bá wo ọ̀tún, ó wo òsì, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Yóo ṣòro pupọ fún àwọn ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun!” Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nítorí gbolohun yìí. Ṣugbọn Jesu tún wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọde, yóo ṣòro pupọ láti wọ ìjọba Ọlọrun! Ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá, jù fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun!” Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pupọ. Wọ́n ń bá ara wọn sọ pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni yóo là?” Jesu tẹjú mọ́ wọn, ó wí pé, “Kò ṣeéṣe fún eniyan, ṣugbọn ti Ọlọrun kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé, kò sí ohun tí Ọlọrun kò lè ṣe.” Peteru bẹ̀rẹ̀ sí wí fún un pé, “Wò ó ná, a ti fi ohun gbogbo sílẹ̀ láti tọ̀ ọ́ lẹ́yìn!” Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kò sí ẹnìkan tí ó fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, tabi ìyá, tabi baba, tabi ọmọ, tabi ilẹ̀, sílẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere, tí kò ní rí ilé, arakunrin ati arabinrin, ìyá ati ọmọ, ati ilẹ̀ gbà ní ọgọrun-un ìlọ́po ní ìgbà ìsinsìnyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé pẹlu inúnibíni ni, yóo sì tún rí ìyè ainipẹkun ní ayé tí ń bọ̀. Ṣugbọn ọpọlọpọ tí ó jẹ́ ẹni iwájú yóo di èrò ẹ̀yìn, àwọn èrò ẹ̀yìn yóo wá di ẹni iwájú.”

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ