Mak 1:9-12

Mak 1:9-12 YBCV

O si ṣe li ọjọ wọnni, Jesu jade wá lati Nasareti ti Galili, a si ti ọwọ́ Johanu baptisi rẹ̀ li odò Jordani. Lojukanna bi o si ti goke lati inu omi wá, o ri ọrun pinya, Ẹmi nsọkalẹ bi àdaba le e lori: Ohùn kan si ti ọrun wá, wipe, Iwọ ni ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi. Loju kan náà Ẹmí si dari rẹ̀ si ijù.

Àwọn fídíò fún Mak 1:9-12