Mik 4

4
Ìjọba Alaafia OLUWA Tí Ó Kárí Ayé
1YIO si ṣe li ọjọ ikẹhìn, a o fi oke ile Oluwa kalẹ lori awọn oke-nla, a o si gbe e ga jù awọn oke kekeke lọ; awọn enia yio si mã wọ́ sinu rẹ̀.
2Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio si wá, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a goke lọ si oke-nla Oluwa, ati si ile Ọlọrun Jakobu; on o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa-ọ̀na rẹ̀: nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu.
3On o si ṣe idajọ lãrin ọ̀pọlọpọ enia, yio si bá alagbara orilẹ-ède rére wi; nwọn o si fi idà wọn rọ ọbẹ irin-itulẹ̀, ati ọ̀kọ wọn rọ dojé: orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède, bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ.
4Ṣugbọn nwọn o joko olukuluku labẹ ajara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ rẹ̀; ẹnikan kì yio si daiyà fò wọn: nitori ẹnu Oluwa awọn ọmọ-ogun li o ti sọ ọ.
5Nitori gbogbo awọn enia ni yio ma rìn, olukuluku li orukọ ọlọrun tirẹ̀, awa o si ma rìn li orukọ Oluwa Ọlọrun wa lai ati lailai.
Israẹli Yóo Pada láti Oko Ẹrú
6Li ọjọ na, ni Oluwa wi, li emi o kó amukun, emi o si ṣà ẹniti a le jade, ati ẹniti emi ti pọn loju jọ;
7Emi o si dá awọn amukun si fun iyokù, emi o si sọ ẹniti a ta nù rére di orilẹ-ède alagbara: Oluwa yio si jọba lori wọn li oke-nla Sioni lati isisiyi lọ, ati si i lailai.
8Ati iwọ, Ile iṣọ agbo agùtan, odi ọmọbinrin Sioni, si ọdọ rẹ ni yio wá, ani ijọba iṣãju; ijọba yio si wá si ọdọ ọmọbinrin Jerusalemu.
9Njẹ kini iwọ ha nkigbe soke si? ọba kò ha si ninu rẹ? awọn ìgbimọ rẹ ṣegbé bi? nitori irora ti dì ọ mu bi obinrin ti nrọbi.
10Ma rọbi, si bi, ọmọbinrin Sioni, bi ẹniti nrọbi: nitori nisisiyi ni iwọ o jade lọ kuro ninu ilu, iwọ o si ma gbe inu igbẹ́, iwọ o si lọ si Babiloni; nibẹ̀ ni a o gbà ọ; nibẹ̀ ni Oluwa yio rà ọ padà kuro lọwọ awọn ọta rẹ.
11Ati nisisiyi ọ̀pọlọpọ orile-ède gbá jọ si ọ, ti nwi pe, jẹ ki a sọ ọ di aimọ́, si jẹ ki oju wa ki o wo Sioni.
12Ṣugbọn nwọn kò mọ̀ erò Oluwa, bẹ̃ni oye ìmọ rẹ̀ kò ye wọn: nitori on o kó wọn jọ bi ití sinu ipaka.
13Dide, si ma pakà, Iwọ ọmọbinrin Sioni: nitori emi o sọ iwo rẹ di irin, emi o si sọ patakò rẹ di idẹ, iwọ o si run ọ̀pọlọpọ enia womu-womu: emi o si yá ère wọn sọtọ̀ fun Oluwa, ati iní wọn si Oluwa gbogbo aiye.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Mik 4: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀