Nigbati Jesu si jade nibẹ̀, awọn ọkunrin afọju meji tọ̀ ọ lẹhin, nwọn kigbe soke wipe, Iwọ ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa.
Nigbati o si wọ̀ ile, awọn afọju na tọ̀ ọ wá: Jesu bi wọn pe, Ẹnyin gbagbọ́ pe mo le ṣe eyi? Nwọn wi fun u pe, Iwọ le ṣe e, Oluwa.
Nigbana li o fi ọwọ́ bà wọn li oju, o wipe, Ki o ri fun nyin, gẹgẹ bi igbagbọ́ nyin.
Oju wọn si là; Jesu si kìlọ fun wọn gidigidi, wipe, Kiyesi i, ki ẹ máṣe jẹ ki ẹnikan ki o mọ̀.
Ṣugbọn nigbati nwọn lọ, nwọn ròhin rẹ̀ yi gbogbo ilu na ká.
Bi nwọn ti njade lọ, wò o, nwọn mu ọkunrin odi kan tọ̀ ọ wá, ti o li ẹmi èṣu.
Nigbati a lé ẹmi èṣu na jade, odi si fọhùn; ẹnu si yà awọn enia, nwọn wipe, A ko ri irú eyi ri ni Israeli.
Ṣugbọn awọn Farisi wipe, agbara olori awọn ẹmi èṣu li o fi lé awọn ẹmi èṣu jade.
Jesu si rìn si gbogbo ilu-nla ati iletò, o nkọni ninu sinagogu wọn, o si nwãsu ihinrere ijọba, o si nṣe iwòsan arun ati gbogbo àisan li ara awọn enia.
Ṣugbọn nigbati o ri ọ̀pọ enia, ãnu wọn ṣe e, nitoriti ãrẹ̀ mu wọn, nwọn, si tuká kiri bi awọn agutan ti ko li oluṣọ.
Nigbana li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Lõtọ ni ikorè pọ̀, ṣugbọn awọn alagbaṣe ko to nkan;
Nitorina ẹ gbadura si Oluwa ikorè ki o le rán awọn alagbaṣe sinu ikorè rẹ̀.