Nigbati Jesu ri ọ̀pọlọpọ enia lọdọ rẹ̀, o paṣẹ fun wọn lati lọ si apa keji adagun.
Akọwe kan si tọ̀ ọ wá, o wi fun u pe, Olukọni, emi ó mã tọ̀ ọ lẹhin nibikibi ti iwọ nlọ.
Jesu si wi fun u pe, Awọn kọ̀lọkọlọ ni ihò, ati awọn ẹiyẹ oju ọrun ni itẹ́; ṣugbọn Ọmọ-enia kò ni ibi ti yio gbé fi ori rẹ̀ le.
Ekeji ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Oluwa, jẹ ki emi ki o kọ́ lọ isinkú baba mi na.
Ṣugbọn Jesu wi fun u pe, Iwọ mã tọ̀ mi lẹhin, si jẹ ki awọn okú ki o mã sin okú ara wọn.
Nigbati o si bọ si ọkọ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tẹ̀le e.
Si wò o, afẹfẹ nla dide ninu okun tobẹ̃ ti riru omi fi bò ọkọ̀ mọlẹ; ṣugbọn on sùn.
Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tọ̀ ọ wá, nwọn ji i, nwọn wipe, Oluwa, gbà wa, awa gbé.
O si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi ṣe ojo bẹ̃, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? Nigbana li o dide, o si ba afẹfẹ ati okun wi; idakẹrọrọ si de.
Ṣugbọn ẹnu yà awọn ọkunrin na, nwọn wipe, Irú enia wo li eyi, ti afẹfẹ ati omi okun gbọ tirẹ̀?
Nigbati o si de apa keji ni ilẹ awọn ara Gergesene, awọn ọkunrin meji ẹlẹmi èṣu pade rẹ̀, nwọn nti inu ibojì jade wá, nwọn rorò gidigidi tobẹ̃ ti ẹnikan ko le kọja li ọ̀na ibẹ̀.
Si wò o, nwọn kigbe soke wipe, Kini ṣe tawa tirẹ, Jesu, iwọ Ọmọ Ọlọrun? iwọ wá lati da wa loro ki o to to akokò?
Agbo ọ̀pọ ẹlẹdẹ ti njẹ mbẹ li ọ̀na jijìn si wọn.
Awọn ẹmi èṣu na si bẹ̀ ẹ, wipe, Bi iwọ ba lé wa jade, jẹ ki awa ki o lọ sinu agbo ẹlẹdẹ yi.
O si wi fun wọn pe, Ẹ mã lọ. Nigbati nwọn si jade, nwọn lọ sinu agbo ẹlẹdẹ na; si wò o, gbogbo agbo ẹlẹdẹ na rọ́ sinu okun li ogedengbe, nwọn si ṣegbé ninu omi.
Awọn ẹniti nṣọ wọn si sá, nwọn si mu ọ̀na wọn pọ̀n lọ si ilu, nwọn ròhin ohun gbogbo, ati ohun ti a ṣe fun awọn ẹlẹmi èṣu.
Si wò o, gbogbo ará ilu na si jade wá ipade Jesu; nigbati nwọn si ri i, nwọn bẹ̀ ẹ, ki o le lọ kuro li àgbegbe wọn.