Mat 8:14-17

Mat 8:14-17 YBCV

Nigbati Jesu si wọ̀ ile Peteru lọ, o ri iya aya rẹ̀ dubulẹ àisan ibà. O si fi ọwọ́ bà a li ọwọ́, ibà si fi i silẹ; on si dide, o si nṣe iranṣẹ fun wọn. Nigbati o si di aṣalẹ, nwọn gbe ọ̀pọlọpọ awọn ẹniti o ni ẹmi èṣu wá sọdọ rẹ̀: o si fi ọ̀rọ rẹ̀ lé awọn ẹmi na jade, o si mu awọn olokunrun larada: Ki eyi ti a ti sọ lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe, On tikararẹ̀ gbà ailera wa, o si nrù àrun wa.

Àwọn fídíò fún Mat 8:14-17