Mat 5:27-48

Mat 5:27-48 YBCV

Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ ko gbọdọ ṣe panṣaga. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wò obinrin kan lati ṣe ifẹkufẹ si i, o ti bá a ṣe panṣaga tan li ọkàn rẹ̀. Bi oju ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi. Bi ọwọ́ ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi. A ti wi pẹlu pe, ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, jẹ ki o fi iwe ìkọsilẹ le e lọwọ. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣe nitori àgbere, o mu u ṣe panṣaga; ẹnikẹni ti o ba si gbé ẹniti a kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga. Ẹnyin ti gbọ́ ẹ̀wẹ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ kò gbọdọ bura, bikoṣepe ki iwọ ki o si mu ibura rẹ ṣẹ fun Oluwa. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ máṣe bura rára, iba ṣe ifi ọrun bura, nitoripe itẹ́ Ọlọrun ni, Tabi aiye, nitori apoti itisẹ rẹ̀ ni, tabi Jerusalemu, nitori ilu ọba nla ni. Ki o maṣe fi ori rẹ bura, nitori iwọ ko le sọ irun kan di funfun tabi dudu. Ṣugbọn jẹ ki ọ̀rọ nyin jẹ, Bẹ̃ni, bẹ̃ni; Bẹ̃kọ, bẹ̃kọ; nitoripe ohunkohun ti o ba jù wọnyi lọ, nipa ibi li o ti wá. Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Oju fun oju, ati ehín fun ehín: Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ máṣe kọ̀ ibi; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba gbá ọ li ẹrẹkẹ ọtún, yi ti òsi si i pẹlu. Bi ẹnikan ba fẹ sùn ọ ni ile ẹjọ, ti o si gbà ọ li ẹ̀wu lọ, jọwọ agbáda rẹ fun u pẹlu. Ẹnikẹni ti yio ba fi agbara mu ọ lọ si maili kan, bá a de meji. Fifun ẹniti o bère lọwọ rẹ; ati lọdọ ẹniti o nfẹ win lọwọ rẹ, máṣe mu oju kuro. Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ, ki iwọ si korira ọtá rẹ. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin; Ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun: nitoriti o nmu õrùn rẹ̀ ràn sara enia buburu ati sara enia rere, o si nrọ̀jo fun awọn olõtọ ati fun awọn alaiṣõtọ. Nitori bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe? Bi ẹnyin ba si nkí kìki awọn arakunrin nyin, kili ẹ ṣe jù awọn ẹlomiran lọ? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe? Nitorina ki ẹnyin ki o pé, bi Baba nyin ti mbẹ li ọrun ti pé.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mat 5:27-48

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa