Mat 5:27-48

Mat 5:27-48 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ ko gbọdọ ṣe panṣaga. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba wò obinrin kan lati ṣe ifẹkufẹ si i, o ti bá a ṣe panṣaga tan li ọkàn rẹ̀. Bi oju ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, yọ ọ jade, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi. Bi ọwọ́ ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi. A ti wi pẹlu pe, ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, jẹ ki o fi iwe ìkọsilẹ le e lọwọ. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba kọ̀ aya rẹ̀ silẹ, bikoṣe nitori àgbere, o mu u ṣe panṣaga; ẹnikẹni ti o ba si gbé ẹniti a kọ̀ silẹ ni iyawo, o ṣe panṣaga. Ẹnyin ti gbọ́ ẹ̀wẹ bi a ti wi fun awọn ará igbãni pe, Iwọ kò gbọdọ bura, bikoṣepe ki iwọ ki o si mu ibura rẹ ṣẹ fun Oluwa. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ máṣe bura rára, iba ṣe ifi ọrun bura, nitoripe itẹ́ Ọlọrun ni, Tabi aiye, nitori apoti itisẹ rẹ̀ ni, tabi Jerusalemu, nitori ilu ọba nla ni. Ki o maṣe fi ori rẹ bura, nitori iwọ ko le sọ irun kan di funfun tabi dudu. Ṣugbọn jẹ ki ọ̀rọ nyin jẹ, Bẹ̃ni, bẹ̃ni; Bẹ̃kọ, bẹ̃kọ; nitoripe ohunkohun ti o ba jù wọnyi lọ, nipa ibi li o ti wá. Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Oju fun oju, ati ehín fun ehín: Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ máṣe kọ̀ ibi; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba gbá ọ li ẹrẹkẹ ọtún, yi ti òsi si i pẹlu. Bi ẹnikan ba fẹ sùn ọ ni ile ẹjọ, ti o si gbà ọ li ẹ̀wu lọ, jọwọ agbáda rẹ fun u pẹlu. Ẹnikẹni ti yio ba fi agbara mu ọ lọ si maili kan, bá a de meji. Fifun ẹniti o bère lọwọ rẹ; ati lọdọ ẹniti o nfẹ win lọwọ rẹ, máṣe mu oju kuro. Ẹnyin ti gbọ́ bi a ti wipe, Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ, ki iwọ si korira ọtá rẹ. Ṣugbọn emi wi fun nyin, Ẹ fẹ awọn ọtá nyin, ẹ sure fun awọn ẹniti o nfi nyin ré, ẹ ṣõre fun awọn ti o korira nyin, ki ẹ si gbadura fun awọn ti nfi arankàn ba nyin lò, ti nwọn nṣe inunibini si nyin; Ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun: nitoriti o nmu õrùn rẹ̀ ràn sara enia buburu ati sara enia rere, o si nrọ̀jo fun awọn olõtọ ati fun awọn alaiṣõtọ. Nitori bi ẹnyin ba fẹ awọn ti o fẹ nyin, ọpẹ́ kili ẹnyin ni? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe? Bi ẹnyin ba si nkí kìki awọn arakunrin nyin, kili ẹ ṣe jù awọn ẹlomiran lọ? bẹ̃ gẹgẹ ki awọn agbowode nṣe? Nitorina ki ẹnyin ki o pé, bi Baba nyin ti mbẹ li ọrun ti pé.

Mat 5:27-48 Yoruba Bible (YCE)

“Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ fún àwọn baba ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obinrin pẹlu èrò láti bá a lòpọ̀, ó ti ṣe àgbèrè pẹlu rẹ̀ ná ní ọkàn rẹ̀. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù. Ó sàn fún ọ pé kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ kí ó ṣègbé jù pé kí á sọ gbogbo ara rẹ sí ọ̀run àpáàdì lọ. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ ó ṣègbé jù kí gbogbo ara rẹ lọ sí ọ̀run àpáàdì lọ. “Wọ́n sọ pé, ‘Ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ níláti fún un ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé ẹni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìjẹ́ pé aya yìí ṣe ìṣekúṣe, ó mú un ṣe àgbèrè. Ẹni tí ó bá sì fẹ́ obinrin tí a kọ̀ sílẹ̀, òun náà ṣe àgbèrè. “Ẹ ti tún gbọ́ tí a sọ fún àwọn baba-ńlá wa pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi ìbúra jẹ́jẹ̀ẹ́ láì mú un ṣẹ. O gbọdọ̀ san ẹ̀jẹ́ tí o bá jẹ́ fún Oluwa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ má ṣe búra rárá; ìbáà ṣe pé kí ẹ fi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọrun ni; tabi pé kí ẹ fi ayé búra, nítorí ìtìsẹ̀ tí Ọlọrun gbé ẹsẹ̀ lé ni. Ẹ má fi Jerusalẹmu búra, nítorí ìlú ọba tí ó tóbi ni; tabi pé kí ẹ fi orí yín búra, nítorí ẹ kò lè dá ẹyọ irun kan níbẹ̀, ìbáà ṣe funfun tabi dúdú. Ṣugbọn kí ‘Bẹ́ẹ̀ ni’ yín jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ ni,’ kí ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́’ yín sì jẹ́ ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́.’ Ohun tí ẹ bá sọ yàtọ̀ sí èyí, ọ̀rọ̀ ẹni-ibi nì ni. “Ẹ ti gbọ́ tí a sọ pé, ‘Nígbà tí o bá fẹ́ gbẹ̀san, ojú dípò ojú ati eyín dípò eyín ni.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹ má ṣe gbẹ̀san bí ẹnikẹ́ni bá ṣe yín níbi. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí ẹnìkan bá gbá yín létí ọ̀tún, ẹ kọ ti òsì sí i. Ẹni tí ó bá fẹ́ pè ọ́ lẹ́jọ́ láti gba àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ, jẹ́ kí ó gba ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ náà. Bí ẹnìkan bá fi agbára mú ọ pé kí o ru ẹrù òun dé ibùsọ̀ kan, bá a rù ú dé ibùsọ̀ keji. Ẹni tí ó bá bèèrè nǹkan lọ́wọ́ rẹ, fi fún un. Má ṣe kọ̀ fún ẹni tí ó bá fẹ́ yá nǹkan lọ́wọ́ rẹ. “Ẹ ti gbọ́ tí a ti sọ pé, ‘Fẹ́ràn aládùúgbò rẹ, kí o kórìíra ọ̀tá rẹ.’ Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí ó ṣe inúnibíni yín. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ti di ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. Nítorí a máa mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere; a sì máa rọ òjò sórí àwọn olódodo ati sórí àwọn alaiṣododo. Nítorí bí ẹ bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín, èrè wo ni ó wà níbẹ̀? Mo ṣebí àwọn agbowó-odè náà a máa ṣe bẹ́ẹ̀. Tí ẹ bá ń kí àwọn arakunrin yín nìkan, kí ni ẹ ṣe ju àwọn ẹlòmíràn lọ? Mo ṣebí àwọn abọ̀rìṣà náà ń ṣe bẹ́ẹ̀! Nítorí náà, bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ti pé ninu ìṣe rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà pé.

Mat 5:27-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan ní ìwòkuwò, ti bà ṣe panṣágà nínú ọkàn rẹ̀. Bí ojú ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè fún ọ kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé, ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sá à ní èrè kí ẹ̀yà ara rẹ kan ṣègbé ju kí a gbé gbogbo ara rẹ jù sí iná ọ̀run àpáàdì. “A ti wí pẹ̀lú pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lé e lọ́wọ́.’ Ṣùgbọ́n èmi sọ èyí fún yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, láìṣe pé nítorí àgbèrè, ó mú un ṣe àgbèrè, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹni tí a kọ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ búra èké bí kò ṣe pé kí ìwọ kí ó mú ìbúra rẹ̀ fún Olúwa ṣẹ.’ Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, ẹ má ṣe búra rárá: ìbá à ṣe fífi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni. Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba Ńlá ni. Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú. Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi. “Ẹ̀yin tí gbọ́ bí òfin tí wí pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’ Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ má ṣe tako ẹni ibi. Bí ẹnìkan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú. Bí ẹnìkan bá fẹ́ gbé ọ lọ sílé ẹjọ́, tí ó sì fẹ́ gba ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú. Bí ẹni kan bá fẹ́ fi agbára mú ọ rìn ibùsọ̀ kan, bá a lọ ní ibùsọ̀ méjì. Fi fún ẹni tí ó béèrè lọ́wọ́ rẹ, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń fẹ́ wín lọ́wọ́ rẹ, má ṣe mú ojú kúrò. “Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ, kí ìwọ sì kórìíra ọ̀tá rẹ̀.’ Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín. Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín ti ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo. Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́? Àti bí ó bá sì jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin yín nìkan ni ẹ̀yin ń kí, kín ni ẹ̀yin ń ṣe ju àwọn mìíràn lọ? Àwọn kèfèrí kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Nítorí náà, ẹ jẹ́ pípé, gẹ́gẹ́ bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa