Mat 4:1-17

Mat 4:1-17 YBCV

NIGBANA li a dari Jesu si ijù lati ọwọ́ Ẹmi lati dán a wò lọwọ Èṣu. Nigbati o si ti gbàwẹ li ogoji ọsán ati ogoji oru, lẹhinna ni ebi npa a. Nigbati oludanwò de ọdọ rẹ̀, o ni, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ ki okuta wọnyi di akara. Ṣugbọn o dahùn wipe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Enia kì yio wà lãyè nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade wá. Nigbana ni Èṣu gbé e lọ soke si ilu mimọ́ nì, o gbé e le ṣonṣo tẹmpili, O si wi fun u pe, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, bẹ́ silẹ fun ara rẹ: A sá ti kọwe rẹ̀ pe, Yio paṣẹ fun awọn angẹli rẹ̀ nitori rẹ, li ọwọ́ wọn ni nwọn o si gbé ọ soke, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbún okuta. Jesu si wi fun u pe, A tún kọ ọ pe, Iwọ ko gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò. Èṣu gbé e lọ si ori òke giga-giga ẹ̀wẹ, o si fi gbogbo ilẹ ọba aiye ati gbogbo ogo wọn hàn a; O si wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi li emi ó fifun ọ, bi iwọ ba wolẹ, ti o si foribalẹ fun mi. Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Pada kuro lẹhin mi, Satani: nitori a kọwe rẹ̀ pe, Oluwa Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, on nikanṣoṣo ni ki iwọ mã sìn. Nigbana li Èṣu fi i silẹ lọ; si kiyesi i, awọn angẹli tọ̀ ọ wá, nwọn si nṣe iranṣẹ fun u. Nigbati Jesu gbọ́ pe, a fi Johanu le wọn lọwọ, o dide lọ si Galili; Nigbati o si jade kuro ni Nasareti, o wá ijoko ni Kapernaumu, eyi ti o mbẹ leti okun li ẹkùn Sebuloni ati Neftalimu: Ki eyi ti a wi lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe, Ilẹ Sebuloni ati ilẹ Neftalimu li ọ̀na okun, li oke Jordani, Galili awọn keferi; Awọn enia ti o joko li òkunkun ri imọlẹ nla; ati awọn ti o joko ni ibi iku ati labẹ ojiji rẹ̀ ni imọlẹ là fun. Lati igbana ni Jesu bẹ̀rẹ si iwasu wipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mat 4:1-17

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa