Ṣugbọn nigbati o ri ọ̀pọ awọn Farisi ati Sadusi wá si baptismu rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, tali o kìlọ fun nyin lati sá kuro ninu ibinu ti mbọ̀?
Nitorina, ẹ so eso ti o yẹ fun ironupiwada:
Ki ẹ má si ṣe rò ninu ara nyin, wipe, Awa ní Abrahamu ni baba; ki emi wi fun nyin, Ọlọrun le yọ ọmọ jade lati inu okuta wọnyi wá fun Abrahamu.
Ati nisisiyi pẹlu, a ti fi ãke le gbòngbo igi na; nitorina gbogbo igi ti ko ba so eso rere, a o ke e lùlẹ, a o si wọ́ ọ jù sinu iná.
Lõtọ li emi nfi omi baptisi nyin fun ironupiwada: ṣugbọn ẹnikan ti o pọ̀ju mi lọ mbọ̀ lẹhin mi, bàta ẹniti emi ko to gbé; on ni yio fi Ẹmí Mimọ́ ati iná baptisi nyin.
Ẹniti atẹ rẹ̀ mbẹ li ọwọ́ rẹ̀, yio si gbá ilẹ ipaka rẹ̀ mọ́ toto, yio si kó alikama rẹ̀ sinu abà, ṣugbọn ìyangbo ni yio fi iná ajõku sun.
Nigbana ni Jesu ti Galili wá si Jordani sọdọ Johanu lati baptisi lọdọ rẹ̀.
Ṣugbọn Johanu kọ̀ fun u, wipe, Emi li a ba baptisi lọdọ rẹ, iwọ si tọ̀ mi wá?
Jesu si dahùn, o wi fun u pe, Jọwọ rẹ̀ bẹ̃ na: nitori bẹ̃li o yẹ fun wa lati mu gbogbo ododo ṣẹ. Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀.
Nigbati a si baptisi Jesu tan, o jade lẹsẹkanna lati inu omi wá; si wò o, ọrun ṣí silẹ fun u, o si ri Ẹmí Ọlọrun sọkalẹ bi adaba, o si bà le e:
Si kiyesi i, ohùn kan lati ọrun wá, nwipe, Eyí ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.