Mat 3:13-17

Mat 3:13-17 YBCV

Nigbana ni Jesu ti Galili wá si Jordani sọdọ Johanu lati baptisi lọdọ rẹ̀. Ṣugbọn Johanu kọ̀ fun u, wipe, Emi li a ba baptisi lọdọ rẹ, iwọ si tọ̀ mi wá? Jesu si dahùn, o wi fun u pe, Jọwọ rẹ̀ bẹ̃ na: nitori bẹ̃li o yẹ fun wa lati mu gbogbo ododo ṣẹ. Bẹ̃li o jọwọ rẹ̀. Nigbati a si baptisi Jesu tan, o jade lẹsẹkanna lati inu omi wá; si wò o, ọrun ṣí silẹ fun u, o si ri Ẹmí Ọlọrun sọkalẹ bi adaba, o si bà le e: Si kiyesi i, ohùn kan lati ọrun wá, nwipe, Eyí ni ayanfẹ ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi.

Àwọn fídíò fún Mat 3:13-17