Mat 27:50-66

Mat 27:50-66 YBCV

Jesu si tún kigbe li ohùn rara, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ. Si wo o, aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán; Awọn isà okú si ṣí silẹ; ọ̀pọ okú awọn ẹni mimọ́ ti o ti sùn si jinde, Nwọn ti inu isà okú wọn jade lẹhin ajinde rẹ̀, nwọn si wá si ilu mimọ́, nwọn si farahàn ọ̀pọlọpọ enia. Nigbati balogun ọrún, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, ti nwọn nṣọ́ Jesu, ri isẹlẹ na, ati ohun wọnni ti ó ṣẹ̀, èru ba wọn gidigidi, nwọn wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li eyi iṣe. Awọn obinrin pipọ, li o wà nibẹ̀, ti nwọn ńwòran lati òkẽrè, awọn ti o ba Jesu ti Galili wá, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u: Ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu ati Jose, ati iya awọn ọmọ Sebede. Nigbati alẹ si lẹ, ọkunrin ọlọrọ̀ kan ti Arimatea wá, ti a npè ni Josefu, ẹniti on tikararẹ̀ iṣe ọmọ-ẹhin Jesu pẹlu: O tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. Nigbana ni Pilatu paṣẹ ki a fi okú na fun u. Josefu si gbé okú na, o si fi aṣọ ọ̀gbọ mimọ́ dì i, O si tẹ́ ẹ sinu iboji titun ti on tikararẹ̀, eyi ti a gbẹ ninu apata: o si yi okuta nla di ẹnu-ọ̀na ibojì na, o si lọ. Maria Magdalene si wà nibẹ̀, ati Maria keji, nwọn joko dojukọ ibojì na. Nigbati o di ọjọ keji, eyi ti o tẹ̀le ọjọ ipalẹmọ, awọn olori alufa, ati awọn Farisi wá pejọ lọdọ Pilatu, Nwọn wipe, Alàgba, awa ranti pe ẹlẹtan nì wi nigbati o wà lãye pe, Lẹhin ijọ mẹta, emi o jinde. Nitorina paṣẹ ki a kiyesi ibojì na daju titi yio fi di ijọ kẹta, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ máṣe wá li oru, nwọn a si ji i gbé lọ, nwọn a si wi fun awọn enia pe, O jinde kuro ninu okú: bẹ̃ni ìṣina ìkẹhìn yio si buru jù ti iṣaju. Pilatu wi fun wọn pe, Ẹnyin ní oluṣọ: ẹ mã lọ, ẹ ṣe e daju bi ẹ ti le ṣe e. Bẹ̃ni nwọn lọ, nwọn si se iboji na daju, nwọn fi edídí dí okuta na, nwọn si yàn iṣọ.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ

Àwọn àwòrán ẹsẹ fún Mat 27:50-66

Mat 27:50-66 - Jesu si tún kigbe li ohùn rara, o jọwọ ẹmí rẹ̀ lọwọ.
Si wo o, aṣọ ikele tẹmpili si ya si meji lati oke de isalẹ; ilẹ si mì titi, awọn apata si sán;
Awọn isà okú si ṣí silẹ; ọ̀pọ okú awọn ẹni mimọ́ ti o ti sùn si jinde,
Nwọn ti inu isà okú wọn jade lẹhin ajinde rẹ̀, nwọn si wá si ilu mimọ́, nwọn si farahàn ọ̀pọlọpọ enia.
Nigbati balogun ọrún, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, ti nwọn nṣọ́ Jesu, ri isẹlẹ na, ati ohun wọnni ti ó ṣẹ̀, èru ba wọn gidigidi, nwọn wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li eyi iṣe.
Awọn obinrin pipọ, li o wà nibẹ̀, ti nwọn ńwòran lati òkẽrè, awọn ti o ba Jesu ti Galili wá, ti nwọn si nṣe iranṣẹ fun u:
Ninu awọn ẹniti Maria Magdalene wà, ati Maria iya Jakọbu ati Jose, ati iya awọn ọmọ Sebede.


Nigbati alẹ si lẹ, ọkunrin ọlọrọ̀ kan ti Arimatea wá, ti a npè ni Josefu, ẹniti on tikararẹ̀ iṣe ọmọ-ẹhin Jesu pẹlu:
O tọ̀ Pilatu lọ, o si tọrọ okú Jesu. Nigbana ni Pilatu paṣẹ ki a fi okú na fun u.
Josefu si gbé okú na, o si fi aṣọ ọ̀gbọ mimọ́ dì i,
O si tẹ́ ẹ sinu iboji titun ti on tikararẹ̀, eyi ti a gbẹ ninu apata: o si yi okuta nla di ẹnu-ọ̀na ibojì na, o si lọ.
Maria Magdalene si wà nibẹ̀, ati Maria keji, nwọn joko dojukọ ibojì na.

Nigbati o di ọjọ keji, eyi ti o tẹ̀le ọjọ ipalẹmọ, awọn olori alufa, ati awọn Farisi wá pejọ lọdọ Pilatu,
Nwọn wipe, Alàgba, awa ranti pe ẹlẹtan nì wi nigbati o wà lãye pe, Lẹhin ijọ mẹta, emi o jinde.
Nitorina paṣẹ ki a kiyesi ibojì na daju titi yio fi di ijọ kẹta, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ máṣe wá li oru, nwọn a si ji i gbé lọ, nwọn a si wi fun awọn enia pe, O jinde kuro ninu okú: bẹ̃ni ìṣina ìkẹhìn yio si buru jù ti iṣaju.
Pilatu wi fun wọn pe, Ẹnyin ní oluṣọ: ẹ mã lọ, ẹ ṣe e daju bi ẹ ti le ṣe e.
Bẹ̃ni nwọn lọ, nwọn si se iboji na daju, nwọn fi edídí dí okuta na, nwọn si yàn iṣọ.