Mat 27:1-31

Mat 27:1-31 YBCV

NIGBATI o di owurọ̀, gbogbo awọn olori alufa ati awọn àgbãgba gbìmọ si Jesu lati pa a: Nigbati nwọn si dè e tan, nwọn mu u lọ, nwọn si fi i le Pontiu Pilatu lọwọ ti iṣe Bãlẹ. Nigbana ni Judasi, ẹniti o fi i hàn, nigbati o ri pe a dá a lẹbi, o ronupiwada, o si mu ọgbọ̀n owo fadaka na pada wá ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgbãgba. O wipe, emi ṣẹ̀ li eyiti mo fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ hàn. Nwọn si wipe, Kò kàn wa, mã bojuto o. O si dà owo fadaka na silẹ ni tẹmpili, o si jade, o si lọ iso. Awọn olori alufa si mu owo fadaka na, nwọn si wipe, Ko tọ́ ki a fi i sinu iṣura, nitoripe owo ẹ̀jẹ ni. Nwọn si gbìmọ, nwọn si fi rà ilẹ amọ̀koko, lati ma sinkú awọn alejò ninu rẹ̀. Nitorina li a ṣe npè ilẹ na ni Ilẹ ẹ̀jẹ, titi di ọjọ oni. Nigbana li eyi ti Jeremiah wolĩ sọ wá ṣẹ, pe, Nwọn si mu ọgbọ̀n owo fadaka na, iye owo ẹniti a diyele, ẹniti awọn ọmọ Israeli diyele; Nwọn si fi rà ilẹ, amọ̀koko, gẹgẹ bi Oluwa ti làna silẹ fun mi. Jesu si duro niwaju Bãlẹ: Bãlẹ si bi i lẽre, wipe, Iwọ ha li Ọba awọn Ju? Jesu si wi fun u pe, Iwọ wi i. Nigbati a si nkà si i lọrùn lati ọwọ́ awọn olori alufa, ati awọn àgbãgba wá, on kò dahùn kan. Nigbana ni Pilatu wi fun u pe, Iwọ ko gbọ́ ọ̀pọ ohun ti nwọn njẹri si ọ? On kò si dá a ni gbolohun kan; tobẹ̃ ti ẹnu yà Bãlẹ gidigidi. Nigba ajọ na, Bãlẹ a mã dá ondè kan silẹ fun awọn enia, ẹnikẹni ti nwọn ba fẹ. Nwọn si ni ondè buburu kan lakoko na, ti a npè ni Barabba. Nitorina nigbati nwọn pejọ, Pilatu wi fun wọn pe, Tali ẹnyin nfẹ ki emi dá silẹ fun nyin? Barabba, tabi Jesu ti a npè ni Kristi? O sá ti mọ̀ pe nitori ilara ni nwọn ṣe fi i le on lọwọ. Nigbati o si joko lori itẹ́ idajọ, aya rẹ̀ ransẹ si i, wipe, Máṣe li ọwọ́ ninu ọ̀ran ọkunrin olododo nì: nitori ìyà ohun pipọ ni mo jẹ li oju àlá loni nitori rẹ̀. Ṣugbọn awọn olori alufa, ati awọn agbàgba yi ijọ enia li ọkàn pada lati bère Barabba, ki nwọn si pa Jesu. Bãlẹ dahùn o si wi fun wọn pe, Ninu awọn mejeji, ewo li ẹnyin fẹ ki emi dá silẹ fun nyin? Nwọn wipe, Barabba. Pilatu bi wọn pe, Kili emi o ha ṣe si Jesu ẹniti a npè ni Kristi? Gbogbo wọn wipe, Ki a kàn a mọ agbelebu. Bãlẹ si bère wipe, Ẽṣe, buburu kili o ṣe? Ṣugbọn nwọn kigbe soke si i pe, Ki a kàn a mọ agbelebu. Nigbati Pilatu ri pe, on ko le bori li ohunkohun, ṣugbọn pe a kuku sọ gbogbo rẹ̀ di ariwo, o bu omi, o si wẹ̀ ọwọ́ rẹ̀ li oju ijọ, o wipe, Ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia olõtọ yi: ẹ mã bojuto o. Nigbana ni gbogbo enia dahùn, nwọn si wipe, Ki ẹjẹ rẹ̀ wà li ori wa, ati li ori awọn ọmọ wa. Nigbana li o da Barabba silẹ fun wọn. Ṣugbọn o nà Jesu, o si fi i le wọn lọwọ lati kàn a mọ agbelebu. Nigbana li awọn ọmọ-ogun Bãlẹ mu Jesu lọ sinu gbọ̀ngan idajọ, nwọn si kó gbogbo ẹgbẹ ọmọ-ogun tì i. Nwọn si bọ́ aṣọ rẹ̀, nwọn si wọ̀ ọ li aṣọ ododó. Nwọn si hun ade ẹgún, nwọn si fi dé e li ori, nwọn si fi ọpá iyè le e li ọwọ́ ọtún: nwọn si kunlẹ niwaju rẹ̀, nwọn si fi i ṣẹsin, wipe, Kabiyesi, ọba awọn Ju. Nwọn si tutọ́ si i lara, nwọn si gbà ọpá iyè na, nwọn si fi lù u li ori. Nigbati nwọn fi i ṣẹsin tan, nwọn bọ aṣọ na kuro lara rẹ̀, nwọn si fi aṣọ rẹ̀ wọ̀ ọ, nwọn si fa a lọ lati kàn a mọ agbelebu.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú Mat 27:1-31