Mat 26:20-54

Mat 26:20-54 YBCV

Nigbati alẹ si lẹ, o joko pẹlu awọn mejila. Bi nwọn si ti njẹun, o wipe, Lõtọ, ni mo wi fun nyin, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn. Nwọn si kãnu gidigidi, olukuluku wọn bẹ̀rẹ si ibi i lẽre pe, Oluwa, emi ni bi? O si dahùn wipe, Ẹniti o bá mi tọwọ bọ inu awo, on na ni yio fi mi hàn. Ọmọ-enia nlọ bi a ti kọwe nipa tirẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na, lati ọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn! iba san fun ọkunrin na, bi o ṣepe a ko bí i. Nigbana ni Judasi, ti o fi i hàn, dahùn wipe, Rabbi, emi ni bi? O si wi fun u pe, Iwọ wi i. Bi nwọn si ti njẹun, Jesu mu akara, o si sure, o si bu u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wipe, Gbà, jẹ; eyiyi li ara mi. O si mu ago, o dupẹ, o si fifun wọn, o wipe, Gbogbo nyin ẹ mu ninu rẹ̀; Nitori eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia fun imukuro ẹ̀ṣẹ. Ṣugbọn mo wi fun nyin, lati isisiyi lọ emi kì yio mu ninu eso ajara yi mọ́, titi yio fi di ọjọ na, nigbati emi o si bá nyin mu titun ni ijọba Baba mi. Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi. Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Gbogbo nyin ni yio kọsẹ̀ lara mi li oru yi: nitoriti a ti kọwe rẹ̀ pe, Emi o kọlù oluṣọ-agutan, a o si tú agbo agutan na ká kiri. Ṣugbọn lẹhin igba ti mo ba jinde, emi o ṣaju nyin lọ si Galili. Peteru si dahùn o wi fun u pe, Bi gbogbo enia tilẹ kọsẹ̀ lara rẹ, emi kì yio kọsẹ̀ lai. Jesu wi fun u pe, Lõtọ ni mo wi fun ọ pe, Li oru yi ki akukọ ki o to kọ iwọ o sẹ́ mi nigba mẹta. Peteru wi fun u pe, Bi o tilẹ di ati ba ọ kú, emi kò jẹ sẹ́ ọ. Gẹgẹ bẹ̃ni gbogbo awọn ọmọ-ẹhin wi pẹlu. Nigbana ni Jesu bá wọn wá si ibi kan ti a npè ni Getsemane, o si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ joko nihinyi nigbati mo ba lọ igbadura lọhúnyi. O si mu Peteru ati awọn ọmọ Sebede mejeji pẹlu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ si banujẹ, o si bẹ̀rẹ si rẹ̀wẹ̀sì. Nigbana li o wi fun wọn pe, Ọkàn mi bajẹ gidigidi titi de ikú: ẹ duro nihinyi, ki ẹ si mã ba mi sọ́na. O si lọ siwaju diẹ, o si dojubolẹ o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yi ki o kọja kuro lori mi, ṣugbọn kì í ṣe bi emi ti nfẹ, bikoṣe bi iwọ ti fẹ. O si tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o bá wọn, nwọn nsùn, o si wi fun Peteru pe, Kinla, ẹnyin ko le bá mi ṣọ́na ni wakati kan? Ẹ mã ṣọna, ki ẹ si mã gbadura, ki ẹnyin ki o má ba bọ sinu idẹwò: lõtọ li ẹmi nfẹ ṣugbọn o ṣe alailera fun ara. O si tún pada lọ li ẹrinkeji, o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi ago yi kò ba le ré mi kọja bikoṣepe mo mu ú, ifẹ tirẹ ni ki a ṣe. O si wá, o si tun bá wọn, nwọn nsùn: nitoriti oju wọn kun fun orun. O si fi wọn silẹ, o si tún pada lọ o si gbadura li ẹrinkẹta, o nsọ ọ̀rọ kanna. Nigbana li o tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wá, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã sùn wayi, ki ẹ si mã simi: wo o, wakati kù fẹfẹ, ti a o si fi Ọmọ-ẹnia le awọn ẹlẹṣẹ lọwọ. Ẹ dide, ki a mã lọ: wo o, ẹniti o fi mi hàn sunmọ tosi. Bi o si ti nsọ lọwọ, wo o, Judasi, ọkan ninu awọn mejila de, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà pẹlu ọgọ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá. Ẹniti o si fi i hàn ti fi àmi fun wọn, wipe, Ẹnikẹni ti mo ba fi ẹnu ko li ẹnu, on na ni: ẹ mú u. Lojukanna o wá sọdọ Jesu, o si wipe, Alafia, Olukọni; o si fi ẹnu ko o li ẹnu. Jesu si wi fun u pe, Ọrẹ́, nitori kini iwọ fi wá? Nigbana ni nwọn wá, nwọn si gbé ọwọ́ le Jesu, nwọn si mu u. Si wo o, ọkan ninu awọn ti o wà pẹlu Jesu nà ọwọ́ rẹ̀, o si fà idà rẹ̀ yọ, o si ṣá ọkan ti iṣe ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke e li etí sọnù. Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Fi idà rẹ si ipò rẹ̀: nitoripe gbogbo awọn ti o mu idà ni yio ti ipa idà ṣegbé. Iwọ ṣebi emi ko le kepè Baba mi, on iba si fun mi jù legioni angẹli mejila lọ lojukanna yi? Ṣugbọn iwe-mimọ́ yio ha ti ṣe ti yio fi ṣẹ, pe bẹ̃ni yio ri?

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ