Nigbati alẹ si lẹ, o joko pẹlu awọn mejila.
Bi nwọn si ti njẹun, o wipe, Lõtọ, ni mo wi fun nyin, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn.
Nwọn si kãnu gidigidi, olukuluku wọn bẹ̀rẹ si ibi i lẽre pe, Oluwa, emi ni bi?
O si dahùn wipe, Ẹniti o bá mi tọwọ bọ inu awo, on na ni yio fi mi hàn.
Ọmọ-enia nlọ bi a ti kọwe nipa tirẹ̀: ṣugbọn egbé ni fun ọkunrin na, lati ọdọ ẹniti a gbé ti fi Ọmọ-enia hàn! iba san fun ọkunrin na, bi o ṣepe a ko bí i.
Nigbana ni Judasi, ti o fi i hàn, dahùn wipe, Rabbi, emi ni bi? O si wi fun u pe, Iwọ wi i.
Bi nwọn si ti njẹun, Jesu mu akara, o si sure, o si bu u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wipe, Gbà, jẹ; eyiyi li ara mi.
O si mu ago, o dupẹ, o si fifun wọn, o wipe, Gbogbo nyin ẹ mu ninu rẹ̀;
Nitori eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia fun imukuro ẹ̀ṣẹ.
Ṣugbọn mo wi fun nyin, lati isisiyi lọ emi kì yio mu ninu eso ajara yi mọ́, titi yio fi di ọjọ na, nigbati emi o si bá nyin mu titun ni ijọba Baba mi.
Nigbati nwọn si kọ orin kan tan, nwọn jade lọ sori òke Olifi.