Mat 25:31-46

Mat 25:31-46 YBCV

Nigbati Ọmọ-enia yio wá ninu ogo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli mimọ́ pẹlu rẹ̀, nigbana ni yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀: Niwaju rẹ̀ li a o si kó gbogbo orilẹ ède jọ: yio si yà wọn si ọ̀tọ kuro ninu ara wọn gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iyà agutan rẹ̀ kuro ninu ewurẹ: On o si fi agutan si ọwọ́ ọtún rẹ̀, ṣugbọn awọn ewurẹ si ọwọ́ òsi. Nigbana li Ọba yio wi fun awọn ti o wà li ọwọ́ ọtun rẹ pe, Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, ti a ti pèse silẹ fun nyin lati ọjọ ìwa: Nitori ebi pa mi, ẹnyin si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin si fun mi li ohun mimu: mo jẹ alejò, ẹnyin si gbà mi si ile: Mo wà ni ìhoho, ẹnyin si daṣọ bò mi: mo ṣe aisan, ẹnyin si bojuto mi: mo wà ninu tubu, ẹnyin si tọ̀ mi wá. Nigbana li awọn olõtọ yio da a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li onjẹ? tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, ti awa fun ọ li ohun mimu? Nigbawo li awa ri ọ li alejò, ti a gbà ọ si ile? tabi ti iwọ wà ni ìhoho, ti awa daṣọ bò ọ? Tabi nigbawo li awa ri ti iwọ ṣe aisan, ti a bojuto ọ? tabi ti iwọ wà ninu tubu, ti awa si tọ̀ ọ wá? Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi. Nigbana ni yio si wi fun awọn ti ọwọ́ òsi pe, Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, sinu iná ainipẹkun, ti a ti pèse silẹ fun Eṣu ati fun awọn angẹli rẹ̀: Nitori ebi pa mi, ẹnyin kò si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin kò si fun mi li ohun mimu: Mo jẹ alejò, ẹnyin kò gbà mi si ile: mo wà ni ìhoho, ẹnyin kò si daṣọ bò mi: mo ṣàisan, mo si wà ninu tubu, ẹnyin kò bojuto mi. Nigbana ni awọn pẹlu yio dahùn wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, tabi ti iwọ jẹ alejò, tabi ti iwọ wà ni ìhoho, tabi ninu aisan, tabi ninu tubu, ti awa kò si ṣe iranṣẹ fun ọ? Nigbana ni yio da wọn lohun wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin kò ti ṣe e fun ọkan ninu awọn ti o kere julọ wọnyi, ẹnyin kò ṣe e fun mi. Awọn wọnyi ni yio si kọja lọ sinu ìya ainipẹkun: ṣugbọn awọn olõtọ si ìye ainipẹkun.

Video for Mat 25:31-46