Mat 25:31-46

Mat 25:31-46 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbati Ọmọ-enia yio wá ninu ogo rẹ̀, ati gbogbo awọn angẹli mimọ́ pẹlu rẹ̀, nigbana ni yio joko lori itẹ́ ogo rẹ̀: Niwaju rẹ̀ li a o si kó gbogbo orilẹ ède jọ: yio si yà wọn si ọ̀tọ kuro ninu ara wọn gẹgẹ bi oluṣọ-agutan ti iyà agutan rẹ̀ kuro ninu ewurẹ: On o si fi agutan si ọwọ́ ọtún rẹ̀, ṣugbọn awọn ewurẹ si ọwọ́ òsi. Nigbana li Ọba yio wi fun awọn ti o wà li ọwọ́ ọtun rẹ pe, Ẹ wá, ẹnyin alabukun-fun Baba mi, ẹ jogún ijọba, ti a ti pèse silẹ fun nyin lati ọjọ ìwa: Nitori ebi pa mi, ẹnyin si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin si fun mi li ohun mimu: mo jẹ alejò, ẹnyin si gbà mi si ile: Mo wà ni ìhoho, ẹnyin si daṣọ bò mi: mo ṣe aisan, ẹnyin si bojuto mi: mo wà ninu tubu, ẹnyin si tọ̀ mi wá. Nigbana li awọn olõtọ yio da a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li onjẹ? tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, ti awa fun ọ li ohun mimu? Nigbawo li awa ri ọ li alejò, ti a gbà ọ si ile? tabi ti iwọ wà ni ìhoho, ti awa daṣọ bò ọ? Tabi nigbawo li awa ri ti iwọ ṣe aisan, ti a bojuto ọ? tabi ti iwọ wà ninu tubu, ti awa si tọ̀ ọ wá? Ọba yio si dahùn yio si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin ti ṣe e fun ọkan ninu awọn arakunrin mi wọnyi ti o kere julọ ẹnyin ti ṣe e fun mi. Nigbana ni yio si wi fun awọn ti ọwọ́ òsi pe, Ẹ lọ kuro lọdọ mi, ẹnyin ẹni egun, sinu iná ainipẹkun, ti a ti pèse silẹ fun Eṣu ati fun awọn angẹli rẹ̀: Nitori ebi pa mi, ẹnyin kò si fun mi li onjẹ: ongbẹ gbẹ mi, ẹnyin kò si fun mi li ohun mimu: Mo jẹ alejò, ẹnyin kò gbà mi si ile: mo wà ni ìhoho, ẹnyin kò si daṣọ bò mi: mo ṣàisan, mo si wà ninu tubu, ẹnyin kò bojuto mi. Nigbana ni awọn pẹlu yio dahùn wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, tabi ti iwọ jẹ alejò, tabi ti iwọ wà ni ìhoho, tabi ninu aisan, tabi ninu tubu, ti awa kò si ṣe iranṣẹ fun ọ? Nigbana ni yio da wọn lohun wipe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, niwọn bi ẹnyin kò ti ṣe e fun ọkan ninu awọn ti o kere julọ wọnyi, ẹnyin kò ṣe e fun mi. Awọn wọnyi ni yio si kọja lọ sinu ìya ainipẹkun: ṣugbọn awọn olõtọ si ìye ainipẹkun.

Mat 25:31-46 Yoruba Bible (YCE)

“Nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá yọ ninu ìgúnwà rẹ̀ pẹlu gbogbo àwọn angẹli, nígbà náà ni yóo jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo péjọ níwájú rẹ̀, yóo wá yà wọ́n sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, bí olùṣọ́-aguntan tíí ya àwọn aguntan sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́. Yóo fi àwọn olódodo sí ọwọ́ ọ̀tún, yóo fi àwọn ìyókù sí ọwọ́ òsì. Nígbà náà ni ọba yóo sọ fún àwọn ti ọwọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bukun. Ẹ wá jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fun yín kí á tó dá ayé. Nítorí nígbà tí ebi ń pa mí, ẹ fún mi ní oúnjẹ. Nígbà tí òùngbẹ ń gbẹ mí, ẹ fún mi ní omi mu. Nígbà tí mo jẹ́ àlejò, ẹ gbà mí sílé. Nígbà tí mo wà níhòòhò, ẹ daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣàìsàn, ẹ wá wò mí. Nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ wá sọ́dọ̀ mi.’ “Nígbà náà ni àwọn olódodo yóo dáhùn pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni a rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a fún ọ ní oúnjẹ, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́ tí a fún ọ ní omi mu? Nígbà wo ni a rí ọ níhòòhò tí a daṣọ bò ọ́? Nígbà wo ni a rí ọ tí o ṣàìsàn, tabi tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a wá sọ́dọ̀ rẹ?’ Ọba yóo wá dá wọn lóhùn pé, ‘Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti ṣe é fún ọ̀kan ninu àwọn arakunrin mi tí ó kéré jùlọ, èmi ni ẹ ṣe é fún.’ “Nígbà náà ni yóo wá sọ fún àwọn tí ó wà ní ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún. Ẹ lọ sinu iná àjóòkú tí a ti pèsè sílẹ̀ fún èṣù ati àwọn angẹli rẹ̀. Nítorí nígbà tí ebi ń pa mí, ẹ kò fún mi ní oúnjẹ jẹ. Òùngbẹ ń gbẹ mí, ẹ kò fún mi ní omi mu. Mo jẹ́ àlejò, ẹ kò gbà mí sílé. Mo wà ní ìhòòhò, ẹ kò daṣọ bò mí. Mo ṣàìsàn, mo wà lẹ́wọ̀n, ẹ kò wá wò mí.’ “Nígbà náà ni àwọn náà yóo bi í pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni a rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́, tabi tí o jẹ́ àlejò, tabi tí o wà ní ìhòòhò, tabi tí o ṣàìsàn, tabi tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a kò bojútó ọ?’ Yóo wá dá wọn lóhùn pé, ‘Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò ti ṣe é fún ọ̀kan ninu àwọn tí ó kéré jùlọ wọnyi, èmi ni ẹ kò ṣe é fún.’ Àwọn wọnyi ni yóo lọ sinu ìyà àìlópin. Ṣugbọn àwọn olódodo yóo wọ ìyè ainipẹkun.”

Mat 25:31-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

“Ṣùgbọ́n nígbà ti Ọmọ Ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn angẹli rẹ̀ nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo ní ọ̀run. Gbogbo orílẹ̀-èdè ni a ó kójọ níwájú rẹ̀, òun yóò sì ya àwọn ènìyàn ayé sí ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn ṣe é ya àgùntàn kúrò lára àwọn ewúrẹ́. Òun yóò sì fi àgùntàn sí ọwọ́ ọ̀tún àti ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì. “Nígbà náà ni ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé. Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’ “Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò fèsì pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ? Tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́ tí a sì fún ọ ní ohun mímu? Tàbí tí o jẹ́ àlejò tí a gbà ó sínú ilé wa? Tàbí tí o wà ní ìhòhò, tí a sì daṣọ bò ọ́? Nígbà wo ni a tilẹ̀ rí i tí o ṣe àìsàn, tàbí tí o wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n, tí a bẹ̀ ọ́ wò?’ “Ọba náà yóò sì dáhùn yóò sì wí fún wọn pé, ‘lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin ṣe nǹkan wọ̀nyí fún àwọn arákùnrin mi yìí tí o kéré jú lọ, ẹ̀ ń ṣe wọn fún mi ni.’ “Nígbà náà ni yóò sọ fún àwọn tí ọwọ́ òsì pé, ‘Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin ẹni ègún, sínú iná àìnípẹ̀kun tí a ti tọ́jú fún èṣù àti àwọn angẹli rẹ̀. Nítorí tí ebi pa mi, ẹ̀yin kò tilẹ̀ bọ́ mi, òrùngbẹ gbẹ mi, ẹ kò tilẹ̀ fún mi ní omi láti mu. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin kò tilẹ̀ gbà mi sílé. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin kò fi aṣọ bò mi. Mo ṣàìsàn, mo sì wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, ẹ̀yin kò bẹ̀ mí wò.’ “Nígbà náà àwọn pẹ̀lú yóò dáhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ, tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òǹgbẹ ń gbẹ ọ́, tàbí tí o ṣàìsàn, tàbí tí o wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, tí a kò sí ràn ọ́ lọ́wọ́?’ “Nígbà náà àwọn yóò dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún pé, Nígbà tí ẹ̀yin ti kọ̀ láti ran ọ̀kan nínú àwọn tí ó kéré jù lọ́wọ́ nínú arákùnrin mi ẹ̀yin tí kọ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún mi ni.’ “Nígbà náà wọn yóò sì kọjá lọ sínú ìyà àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo yóò lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.”