LẸHIN ijọ mẹfa Jesu mu Peteru, ati Jakọbu, ati Johanu arakunrin rẹ̀, o si mu wọn wá sori òke giga li apakan,
Ara rẹ̀ si yipada niwaju wọn; oju rẹ̀ si nràn bi õrùn; aṣọ rẹ̀ si fún, o dabi imọle.
Si wo o, Mose ati Elijah yọ si wọn, nwọn mba a sọ̀rọ.
Peteru si dahùn, o si wi fun Jesu pe, Oluwa, o dara fun wa lati mã gbé ihin: bi iwọ ba fẹ, awa o pa agọ́ mẹta sihin; ọkan fun ọ, ati ọkan fun Mose, ati ọkan fun Elijah.
Bi o ti nwi lọwọ, wo o, awọsanma didán ṣiji bò wọn: si wo o, ohùn kan lati inu awọsanma wá, ti o wipe, Eyiyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dun si gidigidi; ẹ mã gbọ́ tirẹ̀.
Nigbati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́, nwọn da oju wọn bolẹ, ẹru si bà wọn gidigidi.
Jesu si wá, o fi ọwọ́ bà wọn, o si wipe, Ẹ dide, ẹ má bẹ̀ru.
Nigbati nwọn si gbé oju wọn soke, nwọn kò ri ẹnikan, bikoṣe Jesu nikan.
Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, Jesu kìlọ fun wọn pe, Ẹ máṣe sọ̀rọ iran na fun ẹnikan, titi Ọmọ-enia yio fi tun jinde kuro ninu okú.
Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe ha fi wipe, Elijah ni yio tètekọ de?
Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Lõtọ ni, Elijah yio tètekọ de, yio si mu nkan gbogbo pada si ipò.
Ṣugbọn mo wi fun nyin pe, Elijah ti de na, nwọn kò si mọ̀ ọ, ṣugbọn nwọn ti ṣe ohunkohun ti o wù wọn si i. Gẹgẹ bẹ̃ na pẹlu li Ọmọ-enia yio jìya pupọ̀ lọdọ wọn.
Nigbana li o yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li ẹniti o nsọ̀rọ rẹ̀ fun wọn.
Nigbati nwọn si de ọdọ ijọ enia, ọkunrin kan si tọ ọ wá, o kunlẹ fun u, o si wipe,
Oluwa, ṣãnu ọmọ mi, nitori o ni warapa, o si njoro gidigidi: nigba pupọ ni ima ṣubu sinu iná, ati nigba pupọ sinu omi.
Mo si mu u tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ wá, nwọn kò si le mu u larada.
Jesu si dahùn, o wipe, A! iran alaigbàgbọ́ ati arekereke yi, emi o ti ba nyin gbé pẹ to? emi o si ti mu sũru fun nyin pẹ to? Gbé ọmọ na tọ̀ mi wá nihin.
Jesu si ba a wi, ẹmi èṣu na si jade kuro lara rẹ̀; a si mu ọmọ na larada ni wakati kanna.
Nigbana li awọn ọmọ-ẹhin Jesu tọ̀ ọ wá lẹhin, nwọn bi i pe, Ẽṣe ti awa kò fi le lé e jade?
Jesu si wi fun wọn pe, Nitori aigbagbọ́ nyin ni: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Bi ẹnyin ba ni igbagbọ́ bi wóro irúgbin mustardi, ẹnyin o wi fun òke yi pe, Ṣi nihin lọ si ọ̀hun, yio si ṣi; kò si si nkan ti ẹ ki yio le ṣe.
Ṣugbọn irú eyi ki ijade lọ bikoṣe nipa adura ati àwẹ̀.
Nigbati nwọn mbẹ ni Galili, Jesu wi fun wọn pe, A o fi Ọmọ-enia le awọn enia lọwọ