Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin. Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmi rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, yio ri i. Nitoripe ère kini fun enia, bi o jèrè gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmí rẹ̀ nù? tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmí rẹ̀? Nitori Ọmọ-enia yio wá ninu ogo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli rẹ̀; nigbana ni yio san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀. Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihinyi, ti kì yio ri ikú, titi nwọn o fi ri Ọmọ-enia ti yio ma bọ̀ ni ijọba rẹ̀.
Kà Mat 16
Feti si Mat 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 16:24-28
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò