Lati igbana lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ si ifihàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, bi on ko ti le ṣailọ si Jerusalemu, lati jẹ ọ̀pọ ìya lọwọ awọn àgbagbà ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ki a si pa on, ati ni ijọ kẹta, ki o si jinde. Nigbana ni Peteru mu u, o bẹ̀rẹ si iba a wi pe, Ki a ma ri i, Oluwa, kì yio ri bẹ̃ fun ọ. Ṣugbọn o yipada, o si wi fun Peteru pe, Kuro lẹhin mi, Satani, ohun ikọsẹ̀ ni iwọ jẹ fun mi: iwọ ko rò ohun ti iṣe ti Ọlọrun, bikoṣe eyi ti iṣe ti enia.
Kà Mat 16
Feti si Mat 16
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 16:21-23
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò