Mat 16:13-15
Mat 16:13-15 YBCV
Nigbati Jesu de igberiko Kesarea Filippi, o bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẽre, wipe, Tali awọn enia nfi emi Ọmọ-enia ipe? Nwọn si wi fun u pe, Omiran ní, Johanu Baptisti; omiran wipe, Elijah; awọn ẹlomiran ni, Jeremiah, tabi ọkan ninu awọn woli. O bi wọn lẽre, wipe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè?

