Mat 15:32-39

Mat 15:32-39 YBCV

Jesu si pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si ọdọ, o si wipe, Anu ijọ enia nṣe mi, nitoriti o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn ko si li ohun ti nwọn o jẹ: emi kò si fẹ rán wọn lọ li ebi, ki ãrẹ̀ má bà mu wọn li ọ̀na. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Nibo li awa o ti ri akara to li aginjù, ti yio fi yó ọ̀pọ enia yi? Jesu wi fun wọn pe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? Nwọn wipe, Meje, pẹlu ẹja kekeke diẹ. O si paṣẹ ki a mu ijọ enia joko ni ilẹ. O si mu iṣu akara meje, ati ẹja na, o sure, o bù u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si fifun ijọ enia. Gbogbo nwọn si jẹ, nwọn si yó: nwọn si kó ajẹkù ti o kù jọ, agbọ̀n meje kún. Awọn ti o jẹun to ẹgbaji ọkunrin, li aikà awọn obinrin ati awọn ọmọde. O si rán ijọ enia lọ; o si bọ́ sinu ọkọ̀, o lọ si ẹkùn Magdala.

Àwọn Fídíò tó Jẹmọ́ ọ