Nigbati o si de ilu on tikalarẹ, o kọ́ wọn ninu sinagogu wọn, tobẹ̃ ti ẹnu yà gbogbo wọn, nwọn si wipe, Nibo li ọkunrin yi ti mu ọgbọ́n yi ati iṣẹ agbara wọnyi wá? Ọmọ gbẹnagbẹna kọ yi? iya rẹ̀ kọ́ a npè ni Maria? ati awọn arakunrin rẹ̀ kọ́ Jakọbu, Jose, Simoni, ati Juda? Ati awọn arabinrin rẹ̀, gbogbo wọn ki o mba wa gbé nihinyi? nibo li ọkunrin yi ti mu gbogbo nkan wọnyi wa? Bẹ̃ni nwọn kọsẹ lara rẹ̀. Ṣugbọn Jesu wi fun wọn pe, Kò si woli ti o wà laili ọlá, bikoṣe ni ilu ati ni ile on tikararẹ̀. On kò si ṣe ọ̀pọ iṣẹ agbara nibẹ̀, nitori aigbagbọ́ wọn.
Kà Mat 13
Feti si Mat 13
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 13:54-58
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò