Arakunrin yio si fi arakunrin rẹ̀ fun pipa, ati baba yio si fi ọmọ rẹ̀ fun pipa: awọn ọmọ yio si dide si awọn obi wọn nwọn o si mu ki a pa wọn. Gbogbo enia yio si korira nyin nitori orukọ mi; ṣugbọn ẹniti o ba foritì i titi fi de opin, on na ni a ó gbalà. Ṣugbọn nigbati nwọn ba ṣe inunibini si nyin ni ilu yi, ẹ sá lọ si omiran: lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ẹnyin kì ó le rekọja gbogbo ilu Israeli tan titi Ọmọ enia ó fi de. Ọmọ-ẹhin kì ijù olukọ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni ọmọ-ọdọ ẹni ki ijù oluwa rẹ̀ lọ. O to fun ọmọ-ẹhin ki o dabi olukọ rẹ̀, ati ọmọ-ọdọ ki o dabi oluwa rẹ̀. Bi nwọn ba pè bãle ile ni Beelsebubu, melomelo ni awọn ara ile rẹ̀? Nitorina ẹ má fòiya wọn; nitoriti ko si ohun ti a bò, ti ki o farahàn; ati eyi ti o farasin, ti a ki yio mọ̀. Ohun ti mo ba wi fun nyin li òkunkun, on ni ki ẹnyin ki o sọ ni imọlẹ; ati eyi ti ẹnyin gbọ́ si etí ni ki ẹ kede rẹ̀ lori ile. Ẹ má fòiya awọn ẹniti ipa ara, ṣugbọn ti nwọn ko le pa ọkàn: ṣugbọn ẹ kuku fòiya ẹniti o le pa ara ati ọkàn run li ọrun apadi. Ologoṣẹ meji ki a ntà ni owo idẹ kekere kan? bẹ̃ni ko si ọkan ninu wọn ti yio ṣubu silẹ lẹhin Baba nyin. Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan. Nitorina ẹ má fòiya; ẹnyin ni iye lori jù ọ̀pọ ologoṣẹ lọ. Nitorina ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, on li emi o jẹwọ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun. Ṣugbọn bi ẹnikan ba si sẹ mi niwaju enia, on na li emi o sẹ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun. Ẹ máṣe rò pe emi wá rán alafia si aiye, emi ko wá rán alafia bikoṣe idà. Mo wá lati yà ọmọkunrin ni ipa si baba rẹ̀, ati ọmọbinrin ni ipa si iya rẹ̀, ati ayamọ si iyakọ rẹ̀. Awọn ara-ile enia si li ọta rẹ̀. Ẹniti o ba fẹ baba tabi iya jù mi lọ, kò yẹ ni temi: ẹniti o ba si fẹ ọmọkunrin tabi ọmọbinrin jù mi lọ, kò si yẹ ni temi. Ẹniti kò ba si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin, kò yẹ ni temi. Ẹniti o ba ri ẹmi rẹ̀, yio sọ ọ nù; ẹniti o ba si sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi, on ni yio si ri i.
Kà Mat 10
Feti si Mat 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: Mat 10:21-39
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò